Gbajumọ onkọrin Fuji kan to ti doloogbe, Oloye Sikiru Ayinde Barrister, lo kọ ọ lorin ninu ọkan lara awo orin rẹ pe “ọrẹ ko dun bi ọrẹ meji ko ba i tii ja”. O jọ pe ọrọ yii ti ja si ootọ ninu ọrọ awọn eekan olorin Fuji ti gbogbo aye mọ bii ẹni mowo nni, Akorede Babatunde Okunọla, ti ọpọ eeyan mọ si Saheed Oṣupa, ati Wasiu Alabi Ọdẹtọla, t’awọn eeyan mọ si Pasuma, awọn mejeeji yii ti ṣe ọrẹ timọtimọ sẹyin, wọn ba ara wọn ja ija gidi, ti wọn huwa ata ati oju si ara wọn, amọ lọtẹ yii, ọrẹ wọn ti dun mọran-in-mọran-in, koda wọn ti pada sọ ara wọn di ọrẹ imulẹ, ọrẹ korikosun.
Eyi lo fara han ninu ọrọ ikini ti Saheed Oṣupa kọ nipa Pasuma fun ti ayẹyẹ ọjọ-ibi rẹ lọsẹ taa wa ninu rẹ.
Ṣe gbogbo ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun ni Pasuma, tabi Baa Wasi gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ, maa n di ẹni ọdun tuntun loke eepẹ, tawọn ololufẹ rẹ si maa n ki i loriṣiiriṣii.
Amọ fun igba pipẹ sẹyin, paapaa nigba ti aarin awọn mejeeji ko gun rege, ko si eyi to maa n ki ara wọn ninu Paso ati Oṣupa, bẹẹ lawọn ololufẹ kaluku wọn ki i dori ikanni ẹnikeji debi ti yoo ki i, ayafi igba ti ija naa pari.
Eyi ni ọrọ ikini ti Ọba Orin, Saheed Oṣupa, kọ sori ikanni rẹ lati ki ọrẹ rẹ, Pasuma fun ti ayẹyẹ ọjọọbi rẹ lọdun 2024 yii ṣe ya ọpọ eeyan lẹnu, ti wọn si n gboṣuba fun un.
Lori ikanni instagiraamu rẹ ni Oṣupa gbe fidio oun ati ọrẹ atata rẹ yii si lọjọ Wẹsidee, o si kọ ọrọ sibẹ, o ni:
“Mo ki ọrẹ mi, Ajibọla Alabi Pasuma, kuu ọjọọbi o. Mo dupẹ gidigidi pe awa mejeeji ti gbagbe ọrọ ana, a si ti la gbogbo rọfọrọfọ atẹyinwa kọja, eyi to sọ wa di akọni nigbẹyin. Niṣe ni eyi fihan gbangba pe okun ifẹ to so wa pọ latilẹ, okun to nipọn ni.
Ni ọjọ pataki rẹ yii, o wu mi lati ṣapọnle rẹ gẹgẹ bii eeyan amuyangan too jẹ, ki n si fi han gbogbo aye pe ọrẹ atata lawa mejeeji n ba ara wa ṣe.
Inu mi dun jọjọ pe emi atiẹ jọ rin irin-ajo yii papọ ni, a dẹ ṣi ni ọpọ nnkan rere, nnkan ayọ, itan idunnu taa jọ maa ṣe. Mo ba ẹ yọ fun ọdun tuntun too bẹrẹ yii, ọdun ayọ, ọdun igbega ati ajọṣepọ ọrẹ rere ni yoo jẹ.
Ẹ o ranti pe ija orogun owo to gbona janjan lo ti waye laaarin awọn ọrẹ imulẹ mejeeji yii sẹyin, o si fẹrẹ ma si eebu ti wọn ko bu ara wọn tan nigba naa.
Lọdun 2019, lasiko aawẹ Ramadan lo bẹrẹ si i rẹ ija wọn ọhun, nigba ti Sule Alao, tawọn eeyan mọ si Malaika da si i, to si ba awọn mejeeji sọrọ. Lẹyin eyi, nigba ti Mama Pasuma, iyẹn Alaaja Adijat Kuburat ṣalaisi, Oṣupa lọọ ki i, o si tu u ninu gẹgẹ bii ọrẹ tootọ.
Bakan naa ni Paso dupẹ lọwọ Oṣupa, o si tun ki oun naa lọjọọbi rẹ latigba naa wa.
Laipẹ yii, nigba ti awuyewuye tuntun fẹẹ gbode lagboole Fuji, o han gbangba pe Oṣupa nifẹẹ ọrẹ rẹ yii, tori bo ṣe kọrin lowe-lowe to, niṣe lo pe Paso ni Anọbi, o ni ọkan lara awọn Anọbi Ọlọrun nidii iṣẹ Fuji ni, o si da oun loju bẹẹ.
Pasuma naa ti dupẹ lọwọ Oṣupa fun ti ikini ọlọyaya to ki i lọjọọbi rẹ yii. Pasuma fesi pe: “O ṣeun lọpọlọpọ Jakie, Ọla Baba Suliat, mo mọriri eyi o. Ifẹ ni o, Alayinla Kingi kingi.”
Lara awọn to tun kọ ọrọ lati fi idunnu wọn han si irẹpọ tuntun yii ni ọga onimọto nni, Kokozaria, agba oṣere tiata, Iya Rainbow, Bimbọ Thomas, Kẹmi Korede, Mustapha Sọlagbade, Mama Ereko ati bẹẹ bẹẹ lọ.