Itafaaji

Awọn oṣere nlanla daro pẹlu Mercy Aigbe!

Asiko yii ki i ṣe eyi to rọgbọ fun gbajugbaja arẹwa oṣere-binrin onitiata ilẹ wa nni, Mercy Aigbe, niṣe ni ọrọ idaro ati adura ‘Ọlọrun aa fi ofo ra ẹmi’ n rọ bii ojo fun obinrin apọnbeporẹ yii, latari bi ile toun atọkọ rẹ n gbe, ṣe jona guruguru, l’Ekoo.

Ko sẹni ti yoo ri awọn fọto ati fidio to ṣafihan ọṣẹ buruku ti ina ọmọ ọrara ṣe si ile ọhun ti ara aje ko nii ta onitọhun, niṣe ni gbogbo dukia olowo nla, latori aga ijokoo ọlọla, titi kan awọn nnkan eelo abanaṣiṣẹ ati gbogbo ọṣọ ile jona guruguru, titi dori oke aja, gbogbo ara ile naa lo si dudu họhọ fun eefin ati ina runlerunna to waye naa.

ITAFAAJI fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, leyii ti ko ju ọsẹ kan pere ti tọkọ-taya Mercy ati ọkọ rẹ, Alaaji Kazeem Adeoti, yoo ṣafihan fiimu tuntun takọle rẹ jẹ ThinLine, eyi ti wọn fẹẹ ko jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ lọjọ kẹtala, oṣu Kejila yii kan naa,  ni ina ọmọ ọrara ṣọṣẹ ni ile gbajumọ onitiatia yii, to wa l’Erekuṣu Eko.

Ko tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa ina buruku yii, amọ ninu ọkan lara awọn fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, a ri awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana bi wọn ṣe n ṣiṣẹ aṣelaagun lati pa ina ọhun.

Ninu fidio ti Mercy Aigbe gbe soju opo Instagiraamu rẹ, o ṣafihan bi ina yii ṣe jo gbogbo dukia oun atọkọ rẹ deeru patapata. Iran buruku ni iran ọhun, iṣẹlẹ to ṣeni laaanu gbaa ni. Labẹ fidio yii ni Mercy kọ ọrọ ṣoki kan si, o ni: “Eleyii ṣẹrubami o! Mo gbe! Amọ mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko mu ẹmi kankan lọ. Ko buru o.”

Gẹlẹ to gbe fidio ati ọrọ rẹ ọhun sori ayelujara ni awọn ololufẹ rẹ, atawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ ti ya bo o pẹlu awọn ọrọ ibanikẹdun, ati ọrọ imunilọkanle oriṣiiriṣii. O ju ẹgbẹrun mẹwaa atẹjiṣẹ tawọn eeyan kọ lọlọkan-o-jọkan sori ikanni Mercy Aigbe.

Toyin  Abraham, tawọn eeyan mọ si Iya Ire ni: “Jesu! Ọlọrun o! Abajọ to o fi n sunkun lori foonu. Pẹlẹ o, sista mi.”

Adeyinka Alaṣeyọri, obinrin akọrin ẹmi nni, sọ pe: “Jeeesu, o ṣe e. Ko sẹni to ku. Ọlọrun a fi ọpọ rọpo.”

Bisọla Aiyeọla sọ pe: “Ẹ pẹlẹ gidigidi o, Madam. Ọlọrun maa da adanu yin yii pada ni ilọpo-ilọpo o. Ọpẹ nla ni fun Ọlọrun pe ẹmi kankan ko lọ si i.

Ọdunlade Adekọla, ti wọn n pe ni Saamu Alajọ sọ pe: “Jesu Kristi. Ẹ pẹlẹ gidigidi o”.

Yetunde Barnabas ni: “Haa! Ẹ pẹlẹ o, Mama.”

Ede Yoruba ni Kẹmi Afọlabi fi kọ ọrọ tiẹ, o ni: “Bẹkun ba pẹ ti ti, ayọ n bọ laipẹ Insha Allah, Ọrẹ mi.”

Mo Bimpe, iyawo Lateef Adedimeji ni: Haa! Ẹ pẹlẹ Ma o.”

Iyabọ Ojo sọ pe: “Iru kileyi tori Ọlọrun! Ẹ pẹlẹ o, eyi baayan lọkan jẹ ju.” Lẹyin eyi lo tun lọọ sori ikanni rẹ, o si kọ ọrọ ibanikẹdun akanṣe sibẹ, o ni: “Ọrẹ mi ọwọn, Mercy Aigbe, ati Arakunrin mi onirẹlẹ, Kazeem Adeoti, O dun mi gan-an nigba ti mọ gbọ ti iṣẹlẹ to n ko aarẹ-ọkan ba’ni nipa ile yin to jona. Mo fi tọkantọkan kẹdun pẹlu yin lasiko ipenija nla yii. Ẹ jọọ, mo fẹ kẹẹ mọ pe Ọlọrun wa pẹlu yin, o si maa ran yin lọwọ lati kọ ile mi-in to tiẹ tun maa jojunigbese ju eleyii lọ. Adanu yii ki i ṣe opin o, ibẹrẹ ni.” O si gbe fọto tọkọtaya naa si i.

Sikiratu Sindodo, iyẹn Tayọ Odueke sọ pe: “Ọlọrun mi o. Ẹ pẹlẹ gidigidi o.”

Adediwura Blackgold ni: Ọkan mi ba iwọ ati gbogbo awọn eeyan rẹ kẹdun o. Mo gba ẹ mọra, mo si ṣadura fun ẹ. A o nii padanu ẹmi lorukọ Jesu.

Bimpe Akintunde ni: Haa! Agbekẹ oo! A o ma nii ṣofo ẹmi kẹ!”

Bẹẹ bẹẹ lawọn oṣere mi-in bii Itẹlẹ, Jide Awobọna, Ṣeyi Ẹdun, Adeniyi Johnson, Bimbọ Afọlayan, Bukọla Adeẹyọ, Bidemi Kosọkọ, Regina Chukwu, Ronkẹ Odusanya, Tayọ Amọkade ti wọn n pe ni Ijẹbu, ba Mercy Aigbe ati ọkọ rẹ kẹdun, ti wọn si ṣadura fun un pe ‘ile ọba to jo, ẹwa lo bu si i’ l’Ọlọrun yoo fi eyi ṣe fun wọn.

ITAFAAJI naa n ba Mercy Aigbe atọkọ rẹ kẹdun. A ṣadura ki Ọlọrun da ikolọ wọn pada ni ilọpo.    

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search