Eyi lawọn ọrọ iwuri ti Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Amofin Bayọ Lawal sọ nipa ilumọ-ọn-ka onkọrin fuji nni, Saheed Babatunde Akorede, ti ọpọ eeyan mọ si Saheed Oṣupa, Ọba orin, tabi Olufimọ akọkọ.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, nibi ayẹyẹ ayajọ Aṣọ ofi, iyẹn Aṣọ Ofi Day, eyi to waye niluu Isẹyin, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ni eto naa ti waye.
Ọdọọdun ni ilu Isẹyin maa n gbalejo ero rẹpẹtẹ, awọn ọba, ijoye, ọtọọkulu, onile ati alejo ti wọn maa n kopa ninu ayẹyẹ igbelarugẹ aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, bo tilẹ jẹ pe ayẹyẹ naa ko waye ni ọdun 2023.
Ọpọ awọn ọmọ bibi ilu Isẹyin ti wọn wa lẹyin odi ati ilẹ okeere lo maa n wale, lati darapọ nibi ayẹyẹ naa.
Saheed Oṣupa ni olorin ti wọn pe lati da wọn lara ya lọdun yii, Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ lo si ṣoju fun ọga rẹ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde lọjọ naa.
Lasiko to n jiṣẹ ti Gomina Makinde fi ran an, Amofin Lawal sọrọ apọnlẹ nipa Saheed Oṣupa, o ni orin rẹ n maa n gbe aṣa ati ẹwa ilẹ Yoruba larugẹ, o si dun mọ oun ninu jọjọ.
Ninu fidio kan ti Saheed Oṣupa gbe sori ẹrọ ayelujara instagiraamu rẹ, Ọba orin yii fi imọriri rẹ han si ayẹsi ati ọrọ iwuri ti Ijọba ipinlẹ Ọyọ sọ nipa rẹ ọhun.
Saheed ni: “Tiwa ni ka ṣa maa tẹsiwaju si i, ka si maa kọ orin to ṣanfaani kari aye. Awa o kii sọrọ pupọ, a ki i gberaga, orin la fi n sọrọ, orin lo n ṣiṣẹ taakuntaakun fun wa.
Mo dupẹ gidigidi lọwọ yin o, Baba, Ọlọla julọ, Amofin Bayọ Lawal, Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ. Emi ni Ọba Saheed Oṣupa Akorede, Olufimọ Akọkọ.”
Ọgọrọ awọn ololufẹ eekan olorin Fuji yii ni wọn ti fi idunnu wọn han si bi Igbakeji gomina ṣe ṣapọnle Saheed Oṣupa. Bi wọn ṣe kọ ọkan-o-jọkan ọrọ nipa aṣeyọri olorin naa, bẹẹ lawọn mi n ṣeleri pe titi aye awọn, alatilẹyin ati ololufẹ Baba Sulia lawọn yoo jẹ.