Itafaaji

Oloogbe Sheikh Muyideen Ajani Bello: Oniwaasi Agbaye to laya bii kiniun

Itan igbesi-aye Oloogbe Sheikh Muyideen Ajani Bello

Nigba ti okiki iku Ogbontarigi aṣaaju ẹsin musulumi nni, Sheikh Muyideen Ajani Bello gori afẹfẹ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, Kejila, ọdun 2024 yii, bo ṣe n ya ọpọ eeyan lẹnu, bẹẹ lọpọ n mi amikanlẹ pe ọkunrin to fi gbogbo aye rẹ ja fitafita fun itẹsiwaju ẹsin Islam, ti iwaasu rẹ si maa n dabi paṣan lati tọ tolori tẹlẹmu sọna, ati lati ba awọn aṣebajẹ lawujọ wi, lo lọ wẹrẹ yii.

Ọpọ awọn to sun mọ baba agbalagba naa ni wọn royin rẹ gẹgẹ bii afẹdaafẹre ati ẹlẹyinju aanu, to maa n ja fun ẹtọ ọmọniyan ati igbaye-gbadun araalu nigba gbogbo.

Ọkan lara awọn to royin baba naa daadaa ni ilumọ-ọn-ka ajafẹtọọ-ọmọniyan ati ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Majasọla Adeyẹmọ, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho, tabi Igboho Ooṣa.

Sunday Igboho ni: “Ọlọrun Ọba to laye, to lọrun, ko ba mi tẹ Baba mi, Muyideen Ajani Bello, safẹfẹ rere, ko ṣaforijin fun wọn, ko pa aṣiṣe wọn rẹ. Ọjọ Furaidee ti Baba ku fihan pe ẹni Ọlọrun daadaa ni Baba Muyideen Bello.”

Ọdun 1940 ni wọn bi Oloogbe yii siluu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ. Alaaji Bello Ajani ati Alaaja Ubaidat Bello ni awọn obi rẹ. O lọọ ileewe alakọọbẹrẹ ni IDC Primary School, niluu Ibadan, o si kawe-jade nileewe girama. Amọ latigba to ti wa ni majeṣin, ko too lọọ ileewe pamari lo ti nifẹẹ ẹsin Islam, ko si tii pe ọmọọdun mẹwaa to ti n ṣe waasi lasiko aawẹ.

Lẹyin ileewe girama, Muyideen Bello kẹkọọ  imọ ede larubawa ati ẹsin Islam nileewe Mahdul Arabiy School lọdun 1963 si 1967, o gboye Arabic and Islamic theology.

Sheikh Bello ṣiṣẹ olukọni lawọn ileewe ijọba ni ipinlẹ Ọyọ, Ogun ati Kano, o tun ṣiṣẹ tiṣa nileewe girama Ansar-Ur-Deen College to wa niluu Ṣaki, nibi to ti kọ awọn akẹkọọ ni imọ nipa iṣẹda (Biology) ati ti ẹsin Islam.

Nigba to ya, Baba fi iṣẹ tiṣa silẹ, o si gbaju mọ kikọni lẹkọọ ẹsin, eyi to tubọ sọ ọ di gbajumọ kaakiri agbaye. Oun lo wa nipo Missioner fun Ansar-Ud-Deen Society of Nigeria, ẹgbẹ yii lo si lero lẹyin ju lọ ninu ẹsin Islam, lorileede Naijiria.    

Gẹgẹ bi ọpọ awọn ololufẹ baba agbalagba naa ṣe wi, ohun to fa wọn mọra, to si dun mọ wọn ju ni ti ọkan akin ati ootọ inu ti Oloogbe Muyideen Ajani Bello fi n ṣe waasi rẹ. Wọn ni    ẹkọ rẹ maa n yeni, o si maa n soju abẹ nikoo, sibẹ, ki i ṣe ti ọlọrọ wotoworo lasan.

ITAFAAJI ki awọn mọlẹbi ati gbogbo musulumi kuu arafẹraku ẹni wọn yii o.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search