Wọn ti le rẹfirí yii danu, wọn lo fa’gbó lasiko ti ere n lọ lọwọ!

O jọ pe owe Yoruba to ni ‘owo ti àdá mọ ọn ṣe ni i ka àdá léyín’ ti nimuuṣẹ ninu ọrọ alakooso ere bọọlu lori papa kan, Ọgbẹni David Coote, awọn ọga rẹ ti gba iṣẹ rẹfirí to n ṣe lọwọ rẹ, wọn si ti fọwọ osi juwe ọna ile fun un, wọn ni ẹṣẹ rẹ tẹwọn, ko si gba ẹbẹ lasiko yii.

Ajọ to n bojuto awọn alakooso bọọlu lori papa nilẹ Europe, Professional Game Match Officials Limited, PGMOL, ni wọn gbe idajọ wọn kalẹ lodi si Coote, ẹni ọdun mejilelogoji ti wọn fẹsun iwa palapala kan.

Akọkọ ẹsun ti wọn fi kan Rẹfiri yii ni pe, lẹyin ti wọn ti ṣayẹwo awọn fidio kan, wọn fidi rẹ mulẹ pe o sọrọ alufaaṣa, ọrọ eebu nipa ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, wọn lo tun sọrọ aidaa nipa maneja kilọọbu naa, Alagba Jurgen Kloop, fidio ọrọ ibajẹ rẹ ọhun si ti n ja ranyin lori intanẹẹti.

Ẹsun keji ti wọn lọkunrin yii jẹbi rẹ ni pe, kamẹra aṣofofo kan ti wọn wo, fihan pe ninu oṣu Kọkanla to kọja yii, lasiko ti Rẹfiri naa n dari ere bọọlu lọwọ, laarin alafo isinmi ti awọn agbabọọlu fi lọ sinu yara imura wọn lati gbaradi fun igbesẹ keji ifẹsẹwọnsẹ to n lọ lọwọ, wọn ri David Coote ninu yara otẹẹli rẹ toun naa ti lọọ sinmi, nibẹ lo ti n fa elubọ lẹbulẹbu funfun kan s’agbari, bo ṣe n fi kinni naa simu, bẹẹ lo n fa a sagbari, to n sin pẹnṣẹn bii ẹni fa taba, ki idije ọhun too tẹsiwaju. Wọn lawọn fura pe egboogi oloro ni kinni lẹbulẹbu naa, ọmọọya kokeeni, tabi heroine tabi igbo ni, o si lodi sofin fun agbabọọlu tabi alakooso bọọlu lati fagbo lasiko ti ere n lọ lọwọ.

Atigba ti iṣẹlẹ yii ti waye ni wọn ti kọkọ sọ fun un pe ko lọọ rọọkun nile na, ki wọn le raaye ṣe iwadii sawọn ẹsun naa, lati le fidi ododo mulẹ.

Lasiko iwadii wọn ni awọn ẹri mi-in tun jade pe Rẹfiri yii n gba abẹtẹlẹ, wọn ri ijiroro ati atẹjiṣẹ ti oun ati ọrẹ ẹ kan fi ṣọwọ si ara wọn nipa ifẹsẹwọnsẹ kan to fẹẹ waye laaarin ẹgbẹ agbabọọlu Leeds United ati West Bromwich Albion bo tilẹ jẹ pe ọdun 2019 ni eyi ti waye.

Ni abarebabọ iwadii wọn, ajọ PGMOL ni awọn ti gbaṣẹ lọwọ David Coote, awọn si ti le e danu, tori awọn iwa to hu wọnyi tako adehun ati ilana ti wọn fi gba a siṣẹ, bo tilẹ jẹ pe o ṣi lanfaani lati pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, iyẹn to ba gbagbọ pe irọ ni wọn pa mọ oun, to si ni ẹri lati fi gbeja ara rẹ.

Ṣa, ni bayii na, wọn ti gba feere lẹnu rẹfirí David, wọn ni iru ẹ kọ lawọn n fẹ lori papa wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search