Njẹ ẹ ti gbọ ohun ṣẹlẹ si fiimu Funkẹ Akindele tuntun?

Nigba mi-in, ti ohun teeyan ko reti ba ṣẹlẹ lojiji, ti nnkan naa si jẹ nnkan idunnu nla, omije ayọ le gbọn onitọhun, ti yoo bẹrẹ si i da omi loju, fun ayọ to gba ọkan rẹ, iru omije ayọ bẹẹ ti ṣẹlẹ si Funkẹ Akindele, ilumọ-ọn-ka oṣerebinrin onitiata ti ọpọ eeyan mọ si Jẹnifa, latari bi fiimu rẹ tuntun ṣe di igi owo to n so lẹhinkule rẹ bayii. Laaarin ọjọ mejila pere ti fiimu naa gori igba, miliọnu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000m) lo ti rọ da si apo Funkẹ, Iya Ibeji, lobinrin naa ba bu sẹrin-in ayọ, o tun ṣomi loju pẹlu.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, akọsilẹ ti fihan pe fiimu Everybody Loves Jenifa ti Funkẹ ṣẹṣẹ ṣe yii ti di fiimu to ṣe daadaa julọ lori igba fun saa ọdun 2024, latari bi fiimu naa ṣe ṣe daadaa, awọn aye gba tiẹ, ṣibaṣiba lawọn ile sinima n kun fawọn ero rẹpẹtẹ ti wọn wa lati wo o.  

Ṣe Yooba bọ, wọn ni ẹnu onikan la a tii gbọ pọun-un, ati pe inu ẹni ki i dun ka pa a mọra, Funkẹ Akindele, obinrin to fẹran lati maa kopa adẹrin-in poṣonu ninu fiimu yii lo gba ori ikanni Instagiraamu rẹ lọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 to n pari lọ yii, lati fi idunnu rẹ han lori bi fiimu tuntun naa ṣe n ta warawara lawọn ile sinima ti wọn ti lọọ ṣe afihan rẹ, orin ọpẹ ni Funkẹ si mu bọnu, bo ṣe n dupẹ atọkanwa lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri nla yii, bẹẹ lo n gboṣuba fawọn ololufẹ rẹ gbogbo ti wọn ṣugbaa rẹ.

Funkẹ Akindele ni: “O ṣeun o, Oluwa! Ẹ ṣeun gidigidi, gbogbo ẹyin eeyan!! Ko si bi mo ṣe le ri eleyii ṣe ti ko ba si ifẹ ati atilẹyin yin!! Njẹ ki Ọlọrun ba mi bukun fun gbogbo yin o!!!

Ohun iyanu nla to tun ṣẹlẹ ni pe Funkẹ Akindele ko tii dupẹ tan ti fiimu rẹ ọhun tun fi gun ipele tuntun, o ti pa miliọnu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta o le mọkanla, kinni ọhun ko si ti duro, niṣe lo n rọ owo wọle ni kọngbẹ kọngbẹ.

Eyi lo mu ki Funkẹ tun gba ori Instagiraamu rẹ lọ, o wọ ṣokoto penpe ati ẹwu ti wọn kọ akọle fiimu rẹ ọhun si, o ni: Mo dupẹ gidigidi lọwọ gbogbo yin o, ẹyin ololufẹ agbayanu ni Naijiria ati kari aye, fun atilẹyin yin to kọja sisọ.

Mo polongo yin o, ẹyin ẹlẹgbẹ mi ti gbogbo yin lọ soke sodo lati ba mi polowo fiimu yii, tẹẹ tun lọọ ba mi wo o pẹlu awọn ọrẹ yin. Ifẹ tẹẹ ni si mi ati atilẹyin yin lo jẹ ki gbogbo ẹ ṣee ṣe. Si gbogbo ẹyin onitemi, ẹyin fansi mi ati alatilẹyin mi kari aye, mo dupẹ pe ẹ nifẹẹ si Everybody Loves Jenifa.” Bo ṣe n kọ ọrọ yii bẹẹ lo n sọrọ ninu fidio naa, to si n dupẹ ayọ lọwọ gbogbo wọn.

Tẹẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni Funkẹ Akindele jijo ọpẹ nigba ti wọn sọ fun un pe gbogbo tikẹẹti ti wọn tẹ jade pe kawọn eeyan ra, lati wo fiimu naa ni Odeon Cinemas, lorileede United Kingdom, gbogbo tikẹẹti naa ni wọn ra tan patapata laaarin iṣẹju perete, bẹẹ fiimu ọhun ko ti i de. Eyi jọ ‘Sulia kẹn, Ayetoro kẹn’ loju, lo ba bẹrẹ si i dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ ni London. O tun ṣeleri pe oun ti ṣeto bi wọn ṣe maa ṣafikun si awọn tẹlifiṣọn to wa layiika ile sinima naa, ko le tubọ rọrun fawọn ololufẹ oun lati fun oju wọn lounjẹ ki wọn si gbadun owo wọn.

Eyi kọ nigba akọkọ ti fiimu Funkẹ Akindele yoo di igi aje lori igba. Titi di ba a ṣe n sọ yii, Iya Ibeji yii lo ṣi fitan balẹ latari bi fiimu rẹ kan, eyi to pe akọle rẹ ni A Tribe Called Judah, ṣe pawo to fẹrẹ to biliọnu kan aabọ naira (N1.4b) ni ibẹrẹ ọdun yii, wọn ni ko tii si fiimu to pa aduro owo rọgun-rọgun bẹẹ ri ninu itan fiimu agbelewo lorileede yii.

Bakan naa lawọn fiimu mi-in ti Funkẹ Akindele ṣe, bii Battle On Buka Street ati Ọmọ Ghetto The Saga n ṣe bẹbẹ lori igba.

Ọpọ awọn ololufẹ Funkẹ Akindele ni wọn ti n kan saara si i fun aṣeyọri yii, ti wọn si n ba a yọ. Wọn gboṣuba fun obinrin naa nitori aayan ati iwa akinkanju rẹ, wọn lo maa n nawo nara gidigidi sawọn iṣẹ rẹ, ki i roju owo, o si tun maa n fun ọpọ eeyan lanfaani lati darapọ mọ ọn kawọn naa le ri nnkan pọnla nibẹ.

Ẹnikan to kọ ọrọ sabẹ fidio ọpẹ Funkẹ Akindele sọ pe: “Ohun kan to tiẹ daa ju nipa fiimu naa ni pe awọn ọmọ mi le wo o laisi ibẹru pe ki wọn ma lọọ wo iwokuwo tabi aworan onihooho. Iṣẹ nla lo ṣe o, obinrin yii.”

Ṣa, bi wọn ba n ka awọn to maa fi ayọ pari ọdun 2024 yii pẹlu owo tabua, Funkẹ Akindele jẹ ọkan lara wọn, nitori fiimu Everybody Loves Jẹnifa, ti aje n bu igba rẹ jẹ lọwọlọwọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search