Eekan olorin Juju nni, Oloye Ebenezer Obey, lo fun mama naa ni inagijẹ “Cash Madam” ninu awo rẹ to pe ni Board Members, latigba naa si ni orukọ ọhun ti lẹ mọ ọn pẹki.
Bakan naa lawọn olorin bii Yusuf Ọlatunji, Baba Lẹgba, Haruna Iṣọla, Sikiru Ayinde Barrister, Wasiu Ayinde Marshal, Ṣhefiu Alao pokiki Cash Madam laimọye igba fun ẹmi ọlawọ ati oge ṣiṣe rẹ.
Ọpọ awọn ti wọn mọ nipa oge ṣiṣe ati igbelarugẹ aṣa nilẹ Yoruba ni wọn ti n ṣapejuwe iku gbajugbaja oniṣowo ati mama ẹlẹyinju-aanu ọmọ bibi ilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun nni, Alaaja Khadijat Adebisi Edionseri, ti ọpọ eeyan mọ si Cash Madam, gẹgẹ bii opin abala pataki kan ninu itan ilẹ Yoruba.
Ṣibaṣiba lẹsẹ awọn eeyan ja-nkan-ja-nkan niluu Abẹokuta ati agbegbe rẹ pe sibi eto isinku oloogbe naa eyi to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii nile rẹ to wa ninu ọgba GRA, ni Ibara, niluu Abẹokuta.
Afẹmọju ọjọ Mọnde ọhun ni ikede gori afẹfẹ pe Cash Madam ti rebi agba n re lẹni ọdun mọkandinlaaadọrun (89).
Mama n re'le ikẹyin
Adebisi Cash Madam
Wọn ṣadura fun Mama
Awọn alejo ṣedaro
Ninu atẹjade kan ti ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Dokita Adebayọ Adebọwale fi lede lori iku mama wọn, o ni: “Pẹlu ọpẹ atọkanwa si Allah fun igbe aye rere wọn, a kede ipapoda mama wa, maa wa agba, ati mama-mama wa, Ọmọọba-binrin Kadijat Abikẹ Adebisi Edionseri (ọmọ bibi Elegbede) to pada sọdọ ẹlẹdaa rẹ lẹni ọdun mọkandinlaaadọrun-un, lọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2025 lẹyin aisan ra-n-pẹ.”
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti ṣedaro pẹlu awọn mọlẹbi Oloogbe yii. Ninu atẹjade kan ti Oludamọran feto iroyin rẹ, Ọgbẹni Kayọde Akinmade fi lede, Gomina ni adanu nla ni iku Adebisi jẹ fun ipinlẹ Ogun. O ni aṣaaju lobinrin naa jẹ to ba di ọrọ okoowo ṣiṣe, iwa ọlawọ ati aṣeyọri rẹ ko si lẹgbẹ. Bakan naa lo tun sọrọ nipa ẹwa ati oge ṣiṣe rẹ.
Igbakeji Gomina ati Cash Madam
Obey
Gomina Abiodun
KWAM 1
Barrister
Nnkan bii aago meji kọja iṣẹju diẹ ni wọn ti bi yeepẹ bo mama naa laṣiiri ni ile rẹ ọhun, lẹyin ti awọn alaafaa ti kewu si i lara, ti wọn si ti ṣe waasi bo ṣe yẹ, nilana ẹsin Musulumi.
Lara awọn sanmọri ati ọtọọkulu to pesẹ sibi eto isinku naa ni Gomina ipinlẹ Ogun ana, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Olori Adunni Silifat Oyefẹsọ, Iyalaje Akilẹ Ijẹbu, Alaaja Fausat Akorede Alatiṣe, Iyalode Musulumi ipinlẹ Ogun, Igbakeji Gomina tẹlẹri, Alaaja Salimot Badru, Olori ileegbimọ aṣofin Ogun nigba kan, Ọmọọba Surajudeen Adekunbi, Ambasadọ Tunji Iṣọla, Sẹnetọ Gboyega Nasiru Isiaka, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ba a ṣe gbọ Adebisi Edionseri wa lara awọn gbajumọ oniṣowo obinrin to lowo bii ṣẹkẹrẹ titi dọjọ iku rẹ. Lati kekere, nigba to ṣi wa ni majeṣin bii ọmọọdun mẹwaa lo ti mọ ọna okoowo ṣiṣe, pẹlu iranlọwọ ẹgbọn rẹ kan to gbe lọdọ rẹ niluu Badagry nipinlẹ Eko, lọdun 1945. Nigba to ya, obinrin yii di alagbata ọja awọn ileeṣẹ nlanla bii John Holt, UAC, CFAO, Lever Brothers ati bẹẹ bẹẹ lọ. O tun ṣe kọntiraati pipese ounjẹ fawọn ẹlẹwọn fun ọpọ ọdun.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ilu Ibara, l’Abẹokuta ni, to si lọọ ileewe Saint Andrew laye ọjọun, o tun tan mọ agbegbe iku Ayetoro, lagbegbe Yewa, nipinlẹ Ogun.
Alaaja Edionseri
Eekan olorin Juju nni, Oloye Ebenezer Obey, lo fun mama naa ni inagijẹ “Cash Madam” ninu awo rẹ to pe ni Board Members, latigba naa si ni orukọ ọhun ti lẹ mọ ọn pẹki.
Bakan naa lawọn olorin bii Yusuf Ọlatunji, Baba Lẹgba, Haruna Iṣọla, Sikiru Ayinde Barrister, Wasiu Ayinde Marshal, Ṣhefiu Alao pokiki Cash Madam laimọye igba fun ẹmi ọlawọ ati oge ṣiṣe rẹ.