Bi wọn ba pe Mercy Aigbe, oṣere-binrin apọnbeporẹ to tun fẹran okoowo kara-kata ni ọmọ ti wọn n sọ lọwọlọwọ, ko si irọ nibẹ rara ni, nitori fọto ati fidio obinrin naa lo gbode lori ẹrọ ayelujara lasiko yii, bi awọn kan ti n ki i kuu alaja ọdun tuntun 2025, awọn mi-in n ki i kuu ayẹyẹ ọjọọbi rẹ, bẹẹ lo jẹ pe imura rẹ ati bo ṣe polowo ẹwa rẹ, to di arimaleelọ awopadasẹyin lori intanẹẹti lawọn kan ranju mọ, ti wọn si n kan saara
si i pe awẹlẹwa obinrin ni i ṣe.
Ko daju boya Abiọdun wa ninu orukọ ti wọn sọ Mercy Aigbe yii ni kekere rẹ, amọ ọjọ ọdun tuntun, ọjọ kinni oṣu Kinni ni ọjọọbi rẹ, bi gbogbo aye ṣe n ki ara wọn kuu ọdun tuntun, ti wọn n ṣe Api Niu Yia (Happy New Year) bẹẹ lawọn ololufẹ Mercy n ki i pe Api Baidee, ni ajọdun ba di meji lọọdẹ rẹ.
Ọjọọbi ti ọdun 2025 yii lo sọ oṣerebinrin ti fiimu rẹ tuntun n ta warawara lọwọ lasiko yii di ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta (47) loke eepẹ, eyi lo si mu ki obinrin naa di Yeye oge lori ẹrọ ayelujara lati fi idunnu ati idupẹ rẹ han.
Awọn fọto alaranbara to joju ni gbese kan bayii ni Mercy ya loriṣiiriṣii, pẹlu ẹrin ẹyẹ ati iduro akọ rẹ, ọpọ awọn ololufẹ rẹ ni wọn lawọn jẹ dodo ẹwa ati irisi iyawo lọọdẹ ọkọ yii, wọn ni arẹwa to n da ọkọ lọrun ni i ṣe.
Labẹ awọn fotọ ọhun, Mercy Aigbe kọ ọrọ sibẹ, o ni: “Mo ṣilẹkun ọdun kẹtadinlaaadọta o. Ọlọrun lo ni gbogbo iyin, ọpẹ ati ijuba. Mo ki ara mi kuu ọjọọbi o.
Iyabọ Ojo
“Mo ṣilẹkun ọdun kẹtadin-laaadọta o. Ọlọrun lo ni gbogbo ọpẹ”
Laide Bakare
Oṣere naa fẹrẹ ma tii kọ ọrọ yii ti awọn oṣere ẹlẹgbẹ rẹ atawọn ololufẹ rẹ fi bẹrẹ si i rọjo ikini kuu oriire ati adura ọlọkan-o-jọkan si i.
Kunle Afod, Tayọ Amọkade ti ọpọ eeyan mọ si Ijẹbu, titi dori awọn mi-in bii Bobrisky, Adẹrin poṣonu Kie-Kie, Iyabọ Ojo, Bimpe Akintunde, Fausat Balogun ti ọpọ eeyan mọ si Madam Ṣajẹ, Ọmọwunmi Ajiboye, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹ o ranti pe lọjọ kẹtala oṣu Kẹwaa ọdun yii ni Mercy Aigbe ko fiimu rẹ tuntun to pe akọle rẹ ni THINLINE jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ. Ọsẹ kan ṣaaju asiko yii ni ile gbajumọ oṣere yii ṣadeede gbina lagbegbe Magodo, nipinlẹ Eko, ti ina naa si ṣọṣẹ gidigidi, ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye lo ba iṣẹlẹ aburu ọhun rin.
Bakan naa ni Mercy Aigbe tun ṣaroye laipẹ yii pe awọn eeyan kan dẹyẹ si fiimu oun nile sinima, o ni wọn ko jẹ kawọn ololufẹ oun ri fiimu naa wo, niṣe ni wọn n sọ fawọn to fẹẹ ra tikẹẹti pe ko si ẹrọ amuletutu lawọn yara iworan ti wọn ti n ṣafihan fiimu ọhun, tabi ki wọn maa ṣe ipolowo fiimu mi-in fun wọn.
Ṣa, Mercy sọ nisalẹ ọrọ rẹ pe afihan fiimu oun ṣi n lọ lọwọ, ati pe awọn ololufẹ oun gbadun iṣẹ ọpọlọ toun ṣe sibẹ. Bẹẹ lo loun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ibi toun ba a de laye oun, oun si n wọna fun awọn aṣeyọri ọtun laipẹ laijinna, gẹgẹ bo ṣe wi.