Ọlọjọọbi tuntun, Fathia Williams Balogun, ko le pa ayọ rẹ mọra!
Ilumọ-ọn-ka apọnbeporẹ oṣere-binrin onitiata ilẹ wa nni, Faith Balogun, tawọn eeyan tun mọ si Onome Aganga, ti fi idunnu rẹ han si bawọn ololufẹ rẹ ṣe ṣayẹsi rẹ fun ti ajọdun ọjọọbi rẹ lọdun yii.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun 2025 taa wa yii lobinrin naa dẹni ọdun marundinlọgọta (55) loke eepẹ, o si han gbangba pe ayọ ati ọpẹ gba ọkan rẹ gidigidi.
Oriṣiiriṣii awọn fọto to rẹ, pẹlu ọkan-o-jọkan imura oge, nibi ti Fathia ti n paarọ aṣọ bi ọga, lobinrin ọmọ bibi agbegbe Urhobo, ni ipinlẹ Delta naa gbe soju opo Instagiraamu rẹ lori ẹrọ ayelujara, lati fi bi ayọ ọkan rẹ ṣe pọ to han.
Labẹ fọto naa lo kọ ọrọ si, o sọ pe: “Mo n ṣajọyọ bi mo ṣe di ẹni ọdun tuntun loni-in! Ọkan mi kun fun ọpẹ fun gbogbo iriri ti mo ti ni lẹnu irin-ajo aye mi to gbe mi de ipo ti mo wa yii. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun bo ṣe n ran mi lọwọ nigba gbogbo ati fun oore-ọfẹ rẹ eyi ti mo fi n tẹsiwaju. Ṣinkin ni inu mi n dun lori irin-ajo to wa niwaju ati ibukun to n bọ lọna. Ọdun yii, ọdun to maa kun fun ifẹ, ayọ ati aṣeyọri ti ko lopin ni!” Bẹẹ ni Fathia gbe awọn fọto rẹ nibi to ti n rẹrin-in musẹ si i.
Bẹrẹ latori Alesh Sanni, Tayọ Odueke ti wọn n pe ni Sikitatu Sindodo, Tayọ Ṣobọla, iyẹn Ṣotayọ Gaga, Toyọsi Adesanya, Fẹmi Adebayọ ti wọn tun n pe ni Jẹlili oniso, Fausat Balogun ti wọn n pe ni Madam Ṣajẹ, Ronkẹ Oṣodi Oke, Modupẹ Johnson ti ọpọ eeyan mọ si Fali Werepe, Myde Martins, Tayọ Amọkade ti ọpọ eeyan mọ si Ijẹbu, Akin Ọlaiya, Bukunmi Oluwaṣina ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹ kuu oriire ọjọọbi o
Lati ileeṣẹ ITAFAAJI ati QVL, a ba gbajumọ oṣere to fakọyọ, arẹwa Fathia Williams Balogun yọ ayọ ọdun tuntun loke eepẹ. Igba ọdun, ọdun kan, ninu owo, ilera, aṣeyọri ati idunnu, laṣẹ Edumare. Amin!
Ẹ o ranti pe ọsẹ to kọja yii ni Fathia Balogun ati ọkọ rẹ tẹlẹ, Saheed Balogun, toun naa n ṣe ọjọọbi rẹ layajọ ọjọ kannna, ọjọ karun-un, oṣu Keji, dawọ idunnu ayẹyẹ ikẹkọọyege ọmọ wọn kan, Khalid Balogun, to gboye jade ni fasiti Eko, University of Lagos, Unilag. Ki i ṣe pọmọ naa gboye jade lasan, o wa lara awọn to fakọyọ ju lọ ninu ẹkọ rẹ, tori ipo kinni tawọn eleebo n pe ni first class lo mu.
Ọdun 2000 ni Fathia Balogun ati Saidi Balogun, toun naa jẹ agba-oṣere tiata, di tọkọtaya, ti Ọlọrun si fi ọmọ meji ṣikẹ igbeyawo wọn.
Amọ lọdun diẹ sẹyin ni igbeyawo naa fori ṣanpọn, ti awọn mejeeji si kọ ara wọn silẹ. Saidi Balogun fẹyawo mi-in, Fathia naa si pọ soke ra’ja.