Trump di ààrẹ ilè Améríkà, àṣẹ rẹ̀ ńta bá’lé ta b’óko

  Ọ́jọ́ náà rèé bí àná, tí kalukú ń dá-músò, tíwọ́n sì ń yọ̀, níkété tí èsì ètò ìdìbò ààrẹ ilẹ̀ Améríkà tówáyé l’ọdun 2024 jáde pé, ààrẹ ilè náà tẹ́lẹ̀ Donald Trump, tóti lo sáà àkọ́kọ́ gégébí ààrẹ ìkarùnlélógójì l’ọdun 2017 sí odún 2020, ló tún jáwé-oluborí láti di ipò mú gégébí ààrẹ ìkẹtàdínláàdọ́ta l’orile èdè náà.

Níkété tó bèrè ìṣàkóso, sàdéédé ni Donald trump bá laago ìkìlọ, wípé òhun yóò fi ọ̀pọ̀ awọn ààrè, tí wọn kò ní ìwé ìgbélùú  ṣọwọ́ padà si orílẹ-èdè wọn.
       Lọ́gán tí ìkéde náà ṣúyọ, ni kálukú tí àṣẹ náà ta bá, bá bẹ̀rẹ̀ sínii sáré ká, t’ọ́mọ ẹlòmíràn tí kò ríi rò tẹ́lẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sínii pè’lé, bóyá àwọn ará-ilé tíwọ́n mọ̀ pé òún wà nílùú òyìnbó, wọn a jẹ́ bá òun képe Ọlọ́run, láti yí ọkàn ààrẹ Donald trump padà lóríi ìgbẹ́sẹ̀ tó kéde àti gbé ọ̀ún, gégébí Ọlọ́run ti yí ọkàn-an Pharaoh, ọba egipiti, tójẹ́ anini-lára àwọn ọmọ Isreali ní ìgbà nnì padà.

    Gbogbo lọbọlọbọ yìí kò sì yọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀, gẹ́gẹ́bí àṣàa ‘Jápa’ kò ti jìnnà sí ọ̀pọ̀ọ wọn l’ẹ́nu.

Kódà gan, ìwádìí fihàn pé, yàtọ̀ sí àwọn ààrè ọmọ ilẹ̀ Mexico tó jẹ́pẹ́ ònkàa wọn ló pọ̀jù lọ, pèlú egbẹ̀rún-lọ́nà ọ̀tàlénígba-ódín-mẹ́jọ-àti  mẹ́rìnlélógójì, 252,044,

   Nígbàtí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè El Salvador tẹ̀lé ònkà yìí, pèlúu bí àwọ́n náà ti tó ẹgbẹrun mẹ́tàlénígbà, ólé méjìléní-okòó-lé-lẹ́gbẹ̀rin lápapọ̀ 
         Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ònkà wọn fẹ́ẹ wọ, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ólé mẹ́wàá-ódín-lẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rin, làwọn náà wà nínú pákáleke àìní-ìwé-ìgbélùú l’orilede Améríkà.
     Níbí, ìjọba orílè-èdè Améríkà ti lé àwọn èèyàn tí òònkà wọn tayọ, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta-ólé-méjìdínlógójì kúrò, ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kinní, odún 2025, látàríi àṣẹ náà.

   A kò tíì rún ọ̀rọ̀ ìyiùn l’ẹ́nu tán, tí àṣẹ mìíràn tún fi jẹ jáde l’ẹ́nu ààrẹ ilè Améríkà tílùú dìbò yàn, wípé, òhun ti ṣetán báyìí, láti mú àdínkùn bá ìṣúnáa àjọ USAID, ìyiùn àjọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ìdàgbàsókè àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé.

   Kíni àjọ USAID yìí gan, àti ohun tó dúró fún?— a dá àjọ yìí sílẹ̀ lọdún 1960, láti mòó ṣàkóso àwọn ètò ìrànwọ́ fún ọmọnìyàn, l’órúkọ ìjọba ilẹ̀ Améríkà káàkiri agbáyé, yóó sì fẹ́ẹ̀ tó ònkà àwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tóún bá àjọ náà ṣiṣẹ́

   Ọ̀pọ̀ọ wọn lósì fi òkè-òkun ṣebùgbé.

  Àjọ yìí sì ní àwọn ẹ̀ka ní àwọn orílè èdè tólé ní ọgọ́ta níye, gégébí ó ti ṣeún ṣiṣẹ́ ní sàn-án-sàn-án láwọn èka tótó ogúnlọ́gọ̀ mìíràn.

  Ṣùgbọ́n, púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ tí a toríi rẹ̀ dá àjọ yìí sílẹ̀, nni àwọn àjọ mìíràn ṣáàbà mọ́ ń ṣe lórúkọo rẹ̀, tí òhun yóò sì gbọ́ bùkáátà tójẹ́ mọ́ ìnáwó

   Ìwádìí sì fi yé wa pé, Ìjọba ilẹ̀ Améríkà ti ná owó tójẹ́ billionu mejidinlaadorin dollar l’ọdun 2023 látipàṣẹ àjọ USAID, èyí tó fi ń ran àwọn orílé-èdè àgbáyé lówó, pàápàá, àwọn orílè èdè bíi Ukraine, apáa ilẹ̀ Africa, Asia àti Europe.

   Èyí tó mú orílè-èdè náà léwájú gégébíi orílè èdè tóún ṣe ìnáwó lóríi ìgbáyé-gbádùn ọmọnìyàn, púpò nínú owó náà ló jẹ́ ọ̀pọ̀ owó-orí tí àwọn ọmọ ilẹ̀ náà ń san— niwọ́n bá ló tó gẹ́ẹ́

  Bákanáà, tí a bá ń gbọ́ pé, à ń gba abẹ́rẹ́-àjẹsára fún ààrùn r’ọmọ-l’ápá-r’ọmọ-l’ẹ́sẹ̀ táa tún mọ̀ sí POLIO, àjọ USAID ló ṣagbátẹrùu rẹ̀, gégébí ọ̀pọ̀ ìnáwóo rẹ̀ ti dá lórí àwọn ètò ìlera lóníranìran, èyí tóún fojúsun ọ̀nà àti dẹ́kun àwọn àìsàn tó leè mòó jà-ràìnràìn kiri láwọn orílè èdè.

   Àmọ́shá, ọ̀rọ̀ó ti padà bẹ́yìn-yọ o, torípé lénu-lọ́ọ́lọ́ yìí, bí ààrẹ Donald Trump kò ti gbọ́-ìfẹ́é, nni àwọn ọmọ ilẹ̀ Améríkà kan kò ti gbọ́ páà… lóríi bí wọn kò tiṣe fé àjọ náà mọ́
      Àwọn oriṣiríṣi ìdí abáájọ tí ìjọba ilẹ̀ Améríkà se féé yọ báttìrì láraa bàby USAID, lóti sì ti ń ṣúyọ níhìn-ín-l’ọ́hùn-ún

Táa bá sì ní ká wòó, pèlú àwọn òrò tóún ṣúyọ nípa àjọ náà, a kò ní fẹ́ẹ́ kọbi-ara sí àwọn ọ̀nà tí àṣẹ ìdá ètò ìṣúná USAID leè gbà ṣakóbá fún ètò ìlera wa, l’orilede naijiria

 Torípé, àjọ USAID yìí lòún ṣagbátẹrùu àwọn àjọ tóún ṣèwádii ìmọ̀ ijinle sciencì, láti pò oògùn pọ, àti abẹ́rẹ́-àjẹsára, èyítí wọn yóò pín fún àwọn orílè èdè, tí àìsàn kan, tàbí ààrùn míìrán ń báá fínra jọjọ.

   Papàá-jùlọ, orílè èdè Nàìjíríà àtàwon ilẹ̀ adúláwọ̀ mìíràn, niwọ́n n rí ànfààní àjẹsára tí yóò gbógun-ti, ààrùn HIV, àìsàn Ibà àti ikọ́ọ-fée gbà lat’ọdọ àjọ yìí

  Pèlú oríṣiríṣi ọwọ́ tí àwọn orílé-èdè àgbáyé ń yọ

 la wá fi ń jẹ́ẹ lẹ́nu pé, ọ̀nà wo lọ̀nà àbáyọ tí orílè èdè Nàìjíríà yóò fi kúrò ní ipò ìrákòrò, tí yóò sì yé mọ́ọ rọ̀gbọ̀kú-lé àwọn àjọ orílè èdè àgbáyé fún ǹǹkan kan tàbí òmííran, tó ṣe pàtàkì bíi ètò ìlera àti ìgbáyé-gbádùn àwọn aráàlú.

Start typing and press Enter to search