Wọn ti fẹẹ sọ ile Oluwa di ile-ijo ni o – Pasitọ Oyakhilome

Awuyewuye nla ṣẹlẹ laaarin Pastọ Oyakhilome ti ṣọọṣi Christ Embassy ati awọn akọrin ẹmi rẹ

Olùdásílẹ̀ ìjọ Christ Embassy, Pasitọ Chris Oyakhilome ti tan imọlẹ si awuyewuye kan to n ja ranyin nigboro ati lori ẹrọ ayelujara nipa bi awọn gbajumọ onkọrin ẹmi ti wọn ti figba kan wa ninu ṣọọṣi rẹ ṣe ṣadeede dawati, ti wọn fi ile ijọsin naa silẹ lọkọọkan ejeeji, ti omi-in lara wọn si lọọ da ṣọọṣi tirẹ silẹ, Pasitọ Oyakhilome ni otitọ ohun to ṣokunfa kikuro tawọn eeyan naa kuro ko ṣẹyin aiduro deede soju òpó ẹsin ati igbagbọ mọ, o ni wọn ti fẹẹ sọ ṣọọṣi di ile ijo ati ojúkò okoowo, iyẹn ko si ba ilana ẹsin igbagbọ tawọn gbe dani mu.

Sinach
Frank
Praize
Eben

Ọrọ yii jẹ jade lákòókò tí Oyakhilome n ṣalaye lori fọnran kan tó ti di alátagbà lori ẹrọ ayelujara bayii, nipa ìdí tí àwọn akọrin ẹmi taye mọ bii ẹni m’owo bii, Sinach, ẹni ti orúkọ rẹ gan-an n jẹ Osinachi Okoro Egbu, to ti figba kan ri jẹ olórí àwọn akọrin ìjọ náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, Ọgbẹni Frank Edwards, Ọgbẹni Joe Praize àti Ọgbẹni Emmanuel Benjamin, ti ọpọ eeyan mọ si Eben ṣe fi ìjọ Christ Embassy silẹ lairoti. 

Lara ẹsun tawọn eeyan n gbe pooyi ẹnu nipa iṣẹlẹ yii ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe bi ijọ Christ Embassy, ti wọn tun n pe ni Love World International ṣe f’òfin dè awọ́n ọjafafa akọrin ẹmi yii lasiko ti wọn fi wa laaarin wọn, eyi tí kò fún wọn lanfaani làti kọ orin ní ibòmíràn yàtọ̀ sí inu ìjọ náà, ló mú wọn kuku fi ijọ ọhun silẹ pátápátá.

Amọ Pasitọ Chris Oyakhilome ti ni ọrọ ko ri bawọn eeyan ṣe ro o rara, o ni awọn akọrin ẹmi wọnyi, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ wọn ni taarata, o ni wọn ti sọ inú ilé Olúwa di ibi ìpàtẹ ẹ̀bùn, àti ilé-ijó, láì ka ìjọ kún ilé àdúrà, níbi tó yẹ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ati ijọsin ti gba ipo iwaju.

O lawọn to yapa ọhun ko jèrè ọkàn fún Oluwa bó ti wù kó mọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ni wọ́n ń darí orin ọpẹ́ nínú ṣọọṣi, o ni ni kete ti wọn ba ti kọrin tan, to ba ti to akoko láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà, níṣe ni wọn a dawati nile ìjọsìn, wọn ti ba tara wọn lọ.

Oyakhilome
Christ Embassy

Fún àpẹẹrẹ, ọkan ninu awọn akọrin ìjọ náà, Sinach, ni kò fi gbogbo ara sí nínú ìjọ náà mọ́, agaga lati igba ti ijọ olorin ẹmi tó dá sílẹ̀, ìyẹn Sinach International Music Ministry ti bẹrẹ si i gbèrú, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ni ọrọ ijọ ti Sinach ṣedasilẹ rẹ yii ko dun mọ Oyakhilome ninu, wọn lo ti gbiyanju lati pe akọrin naa pada sọdọ rẹ, amọ ko bọ si i. 

Oyakhilome
Sinach
Eben

Ọlọrun lo ba oun sọrọ lati tọ wọn si ọna to tọ, koun si fi eyi ti ko tọ han wọn, amọ nitori wọn ti di gbajumọ, wọn kó fẹẹ darí orin ẹ̀mí nínú ìjọ mọ́. Amọ ṣa o, Oyakhilome ni oun ṣi gbagbọ pe o ṣee ṣe ki wọn yi pada, ki wọn si di atunbi to ba ya, gẹgẹ bo ṣe wi. 

Ninu ọrọ rẹ, Chris Oyakhilome bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn akọrin ìhìnrere náà lórí bí wọ́n ti sọ ẹ̀bun wọn di okoowo lati fi pawo, tí wọ́n sì ń gba owó kí wọn kó tóó kọrin nínu ìjọ, ati pe wọn n ṣe àmúlùmálà ati àdàlù àwọn orin tí wọ́n ń kọ nínú ayé lati wọ inu orin ẹmi ti wọn kọ ninu ìjọ.

Oludasilẹ naa ni oun ti fìgbà kan gbárùkù tì àwọn akọrin ẹmi náà, kó tóo di pé òhun yí padà lórí àti maa polówó orin wọn, nigba ti wọn kùnà làti tẹ̀lé ẹ̀mi tóún dárí loun ṣe fi wọ́n sílẹ̀, ki wọn lọọ ṣe ohun to wu wọ́n.

Praize
Oyakhilome

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ITAFAAJI ko tii lanfaani lati gbọ tẹnu awọn akọrin ẹmi tọrọ kan yi, bẹẹ ni wọn ko tii sọrọ lori awọn ẹsun ti wọn fi ka wọn ọhun. 

Ọdun 1987 ni Pasitọ Chris Oyakhilome, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Edo, ṣe’dasilẹ ijọ Love World ti wọn tun n pe ni Christ Embassy. Ilu Eko, lorileede Naijiria ni olú-ìléejọsìn náà wà, amọ lati igba naa wa, ijọ ọhun ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ di ìjọ ńlá lágbàyé, pẹlu awọn ẹka rẹ to wa láwọn orílè èdè mì-in.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search