Android tabi iPhone, gbogbo wọn lo le bẹrẹ si i gbona bii ajere lojiji, eyi si lewu!
Ko sẹni tinu rẹ ki i dun to ra foonu tuntun, tabi ti wọn fun un lẹbun rẹ, nnkan ayọ nla ni. Awọn foonu igbalode, ti wọn n pe ni smartphone lede oyinbo ti fẹrẹ di apakan igbesi aye awa ẹda. Eyi lo fi jẹ pe yatọ si igba teeyan ba n sun, awọn ẹrọ alagbeeka wọnyi ki i yaayan lẹsẹ kan, bi igbin fa, ikarawun aa tẹle ni i.
Ọkan lara iṣoro ti ẹrọ alagbeeka maa n ni ni bo ṣe maa n ṣadeede gbona lodi-lodi. Ni tododo, ko buru bi foonu ba lọ wọọ-wọọ, to gbona fẹẹrẹfẹ lẹẹkọọkan lasiko to ba n ṣiṣẹ lọwọ. Fun apẹẹrẹ, ti batiri foonu ba n gba okun lati inu ina ẹlẹntiriiki, tabi ti wọn n ṣaaji rẹ, o maa gbona diẹ tayọ bo ṣe maa n ri nigba ti ko ba si ninu ina.
Amọ bi foonu ba ṣadeede gbona geregere, ti iwọn igbona naa fẹrẹ maa joni lọwọ, iṣoro nla ni eleyii, o si lewu gidigidi. Ẹ jẹ ka wo awọn nnkan to maa n fa iru iṣoro yii.
Shane Britton, onimọ nipa ilo foonu Samsung sọ pe nnkan meji to saaba maa n ṣokunfa ki foonu maa gbona bii ajere ko kọja batiri foonu naa ati ẹrọ to n ṣe kokaari iṣẹ foonu, eyi tawọn eebo n pe ni processor rẹ. O ni nigbakuugba ti nnkan mejeeji yii ba ti ṣiṣẹ laisinmi ni igbona odi maa n de ba foonu. Lara awọn nnkan ti Sharon sọ pe o maa n ṣokunfa iṣẹ aṣekudorogbo fun batiri ati processor ni keeyan maa fi foonu gba geemu fun akoko gigun, keeyan maa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ lasiko kan naa lori foonu, titan ẹrọ intanẹẹti ajọlo, iyẹn hotspot, silẹ fawọn mi-in, tabi ki awọn aapu rẹpẹtẹ maa ṣiṣẹ lọ labẹnu lori foonu lasiko kannaa. Ohun mi-in tun ni keeyan fi foonu si ibi ti ina ti n ra a tabi ti oorun ti n pa a.
Ki waa ni ojuutu si foonu to n gbona geregere lodi-lodi yii?
Ki waa ni ojuutu si foonu to n gbona geregere lodi-lodi yii?
Sharon ni, ti batiri foonu rẹ ba ti darugbo, tabi to ti ṣiṣẹ lilagbara fun ohun to ju ọdun meji lọ, tete ṣeto lati paarọ batiri naa.
Amọ bi batiri foonu rẹ ba ṣi wa daadaa, yoo dara lati wo awọn aapu to wa lori foonu rẹ finnifinni, bi eyikeyii ninu wọn ba wa ti o o ki i lo lemọlemọ, tabi ti oo tiẹ mọ iwulo rẹ debi ti waa fọwọ kan, ṣeto lati yọ iru awọn aapu bẹẹ danu. Sharon ni, ọpọ lara awọn aapu yii maa n ṣiṣẹ lọ labẹnu teeyan ko mọ, ọpọ igba lo si jẹ pe boo ṣe n tan foonu rẹ lawọn naa ti bẹrẹ iṣẹ labẹnu, ti wọn yoo maa ko aarẹ ba batiri ati ọpọlọ foonu.
Amọran mi-in tun nipe keeyan ṣakiyesi asiko ti foonu naa maa n gbona odi. Bo ba jẹ pe nigba ti geemu n lọ lọwọ ni, tabi lasiko teeyan n ya fidio ni, o ni lati jẹ pe agbara ọpọlọ foonu yẹn kere si iru geemu ati fidio yiya bẹẹ, o maa dara keeyan paarọ foonu naa, tabi ka maṣe lo o fun geemu ati fidio bẹẹ.
Awọn ogbonkangi onimọ nipa foonu, Thomas Shifflet ati Samuel George naa sọrọ nipa ohun teeyan gbọdọ ṣe ti foonu ba ṣadeede gbona lala. Lara aba wọn ni: ‘Pa foonu rẹ lẹsẹkẹsẹ, ṣi ẹyin rẹ to ba ṣee ṣe ko o si fi ẹyin naa le itan tabi apa rẹ, eyi maa jẹ ko tete tutu bi ko ba si abẹbẹ nitosi. Din imọlẹ oju foonu rẹ ku. Yọ awọn aapu ti ko ba wulo fun ọ danu. Maa fi foonu si Airplane Mode nigbakuugba ti o ko ba ti lo o. Ṣọra fun fifi foonu rẹ sori tabi si ẹgbẹ awọn ẹrọ igbalode bii kọmputa tabi kọmputa alagbeletan nigba gbogbo. Maṣe fi foonu si itosi ile idana tabi ẹrọ to maa n gbona. Maṣe maa wo fidio taarata latori intanẹẹti fun akoko gigun, eyi tawọn eleebo n pe ni streaming, ohun to dara ni koo kọkọ waa fidio naa jade, ko too bẹrẹ si i wo o, ayafi to ba jẹ iṣẹlẹ tabi iran ti wọn n ṣe lọwọ (live events)’.