Ademọla Lookman ni oun ki i sọrọ, amọ kooṣi yii fẹẹ tọwọ bọ oun lẹnu!
Afi bii igba ti awọn ọmọde ba fẹẹ fi oko ka ọsan lori igi, bẹẹ ni bi oko ọrọ ṣe n fo lọtun-un losi lasiko yii ninu ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta, latari bi Ọga Agba kilọọbu naa, Ọgbẹni Gian Piero Gasperini ṣe fibinu sọrọ alufaaṣa si ẹlẹsẹ ayo rẹ, Ademọla Lookman, n ni Lookman naa ba fibinu fesi ọrọ si i lakọ-lakọ, ọrọ yii si ti di eyi tawọn agbabọọlu mi-in atawọn ololufẹ wọn n gba bii ẹni gba igba ọti.
to ṣẹlẹ ni pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025 yii, ikọ agbabọọlu Atalanta, ti Ademọla n gba bọọlu fun lọwọ iwaju, wà á kò pẹlu ikọ agbabọọlu Club Brugge lati mọ ẹni ti yoo wọle fun anfaani béléńjá to ṣi silẹ lati dije fun ife-ẹyẹ Champions League ti ọdun yii. Ifẹsẹwọnsẹ yii lawọn eleebo n pe ni “play off,” o si ti di dandan lowo ori, ọran-an-yan laṣọ ibora fun ikọ agbabọọlu mejeeji lati bori, bi wọn ba ṣi fẹẹ tẹsiwaju.
Bẹẹ si ree, ifẹsẹwọnsẹ bii mẹfa lo ti waye, eyi ti ko ṣee ṣe fun Ademọla Lookman lati kopa ninu rẹ, niṣe lo n woran wọn lori ibusun rẹ tabi ko dara pọ mọ awọn ero iworan lori papa, latari bo ṣe fara ṣeṣe lori papa lọsẹ diẹ sẹyin, to si n gba itọju lọwọ.
Amọ ọjọ buruku ni ọjọ Tusidee naa jẹ fun awọn Atalanta, ohun ti wọn reti kọ ni wọn ba nigba ti ifẹsẹwọnsẹ bẹrẹ, Club Brugge ko ṣaanu wọn rara, láfarabara ni wọn rọjo bọọlu sinu awọn Atalanta, ami-ayo mẹta si odo lo ti wọle sinu nẹẹti wọn nigba ti igbesẹ akọkọ yoo fi pari.
Bi Atalanta ṣe n ṣe kayeefi pe ‘ki lo ṣẹlẹ? iru ki lawọn kan yii kẹ!’ maneja wọn, Ọgbẹni Gasperini sare gbe Ademọla Lookman wọle nigba ti igbesẹ keji bẹrẹ, ọdọmọkunrin naa si fakọyọ nibẹrẹ, koda o fitan balẹ, nitori ko tii pe iṣẹju kan, koda ko ju iṣẹju aaya mẹtalelọgbọn pere lọ ti ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn yii fi gba bọọlu s’áwọ̀n alatako wọn, eyi si mu ki kawọn ti wọn ti sọretinu bẹrẹ si i woye pe adiẹ to ku ṣi le jẹ agbado.
Nigba ti Ọlọrun yoo tun ba wọn ṣe e, rẹfiri fọn feere pe Club Brugge ti ṣeka fun ọmọ Atalanta kan nitosi oju ile wọn, o ni ki Atalanta waa gba bọọlu ‘goli wo mi ki n gba a s’awọn’ ti wọn n pe ni penalty.
Lookman lo gba penalty naa, apa osi rẹ nibi ikangun oju ile naa lo gba a si, amọ o jọ pe bọọlu naa ko sare daadaa to, nitori pẹlu irọrun ni amule Club Brugge fi lọọ pade rẹ, ni golikipa naa ba mu un bọ́kẹ́. Bayii lo ṣe di pe ko tun sẹni to gba bọọlu s’áwọ̀n ninu ikọ mejeeji mọ titi ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi pari, ami ayo mẹta si ookan lo pari si, ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta si fidi rẹmi poo.
O jọ pe bi wọn ṣe fidi rẹmi yii lo ka Maneja Gasperini lara to fi fibinu sọko ọrọ si Lookman nigba ti wọn ṣe tan, o ni: “Aa, mi o tii ri ẹni to gba penalty bii arindin to Ademọla Lookman yii ri o. Bawo leeyan ṣe maa ni oun fẹẹ gba penalty lẹyin to ti gba bọọlu s’áwọ̀n tan. Retegui ati De Keteleare wa nibẹ to yẹ ki wọn gba penalty yẹn. Mi o nifẹẹ si ohun ti Lookman ṣe yii rara.”
“Aa, mi o tii ri ẹni to gba pẹnalty bii arindin to Ademọla Lookman yii ri o! Bawo leeyan ṣe maa ni oun fẹẹ gba penalty lẹyin to ti…”
Ọrọ kobakungbe yii bi Lookman ninu gidigidi, ko si ri ara gba a si rara. Loju opo X rẹ lo gba lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun oṣu yii lati fesi fun Maneja to fiwọsi lọ ọ, o ni: “O ba mi lọkan jẹ gidigidi pe mo ni lati sọ ohun ti mo fẹẹ sọ yii, paapaa nitori ọpọ aṣeyọri ta a ti jọ ṣe papọ gẹgẹ bii ikọ agbabọọlu kan, ta a ti di ilu kan. Ki wọn doju sọ ẹnikan, ki wọn si sọrọ si i ṣakaṣaka bii temi yii maa n mu ọkan eeyan gbọgbẹ, ko si bọwọ funni rara. Wọn o tiẹ ro ti iṣẹ aṣelaagun ati afọkanṣe ti mo n ṣe lojoojumọ ati ni gbogbo igba. Ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn n sọrọ rẹ yii, awọn ti wọn yan lati maa gba penalty naa lo sọ fun mi emi ni ki n gba a o, mo si gba a lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ agbabọọlu wa ni o.” Ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn ololufẹ ere bọọlu alafẹsẹgba ti n sọ nipa iṣẹlẹ yii, ọpọ lo si koro oju si ọrọ alufaaṣa ti Maneja Gian Piero Gasperini sọ si Ademọla Lookman, to jẹ oun lo gba awọọdu agbabọọlu to fakọyọ julọ nilẹ Afrika lọdun 2024, to si tun ko ipa ribiribi lati jẹ ki Atalanta gba ife-ẹyẹ fungba akọkọ lọdun to kọka, lati aimọye ọdun sẹyin.
Ọgbẹni Timmy Denny ni: Ọrọ buruku ni eyi ti Maneja Atalanta sọ yii o. Koda Messi, CR7, Mbappe, Vini, gbogbo awọn lookọlookọ lo ti gba penalty sigbo ri, amo oo le gbọ ki kooṣi wọn sọrọ abuku si wọn bii eyi ti Gasperini sọ yii.”
Titi di ba ṣe n sọ yii lọrọ iṣẹlẹ yii ṣi n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara.