Ẹ ṣaanu mi, aisan yii fẹẹ pa mi! – Halimah Abubakar

Iru Aisan Wo Lo Nse oṣere-binrin tiata yii?

Gbajugbaja oṣere-binrin tiata nni, Halimah Abubakar ti ṣalaye iṣoro ailera to n la kọja, ohun ti oju rẹ ri lori ailera ọhun ati bi awọn ọrẹ ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ṣe dẹyẹ si i, ti wọn pa a ti lori adojukọ ọhun. Ni bayii, o n rawọ ẹbẹ fun iranlọwọ awọn ẹlẹyinju-aanu gbogbo.

Ninu fidio kan to fi lede lori ikanni Instagiraamu rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii, niṣe ni arẹwa oṣere-obinrin naa n wa ẹkun mu pẹlu ẹdun ọkan, o fi aidunnu rẹ han lori bawọn kan ṣe  ro pe irọ l’oun n pa lori aisan oun. O ni oun ti n ba aisan yii ja fun ọjọ pipẹ, toun fi i ṣe iso inu ẹku, eyi to mu kawọn kan gbagbọ pe niṣe loun n dibọn, bẹẹ niṣe loun kan n tiraka lati maa gbe igbe aye oun lọ ni bo ba ṣe gba ni, amọ ootọ ibẹ ni pe ara oun ko ya rara.

Bayii lo ṣe sọ ọrọ rẹ ọhun, o ni: “Ohun to n ṣẹlẹ n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi. Ara mi ko dara titi di isinsinyi, mo kan mọ beeyan ṣe n kora giri ni. Bayii ni mo ṣe ti n ba a yi, ṣugbọn mo n lo awọn nnkan to n jẹ ki irisi mi ṣe e ri, ki n jọ-ọ-yan diẹ, ni mo fi le fi aworan mi sita.

Bi mo ṣe ri gan-an lẹ n wo yii. Awọn eeyan waa n fi mi ṣe yẹyẹ. Ki lo yẹ ko ba yẹyẹ wa? Awọn kan tiẹ n sọ pe irọ ni mo n pa. Bawo ni mo ṣe le fi ọrọ ailera mi purọ? Bawo ni mo ṣe maa fi iru ẹ purọ?”

“Mo nilo iranlọwọ bayii, o ti su mi. Mi o fẹẹ maa tọrọ owo kiri mọ!”

Halimah tun sọ bi aisan naa ṣe ti sọ oun di ẹdun arinlẹ, toun ti padanu owo ati dukia oun, o ni: “Owo ti mo ti na si aisan yii ko mọ niwọn o, ko si owo lọwọ mi mọ. Odidi ọdun kan ni mo lọọ lo ni abule kan, amọ mo tun ni lati pada si igboro nitori ile iwosan ti mo n lo.”

Nigba to n sọrọ nipa iṣẹ tiata rẹ, o ni “O ti to ọdun mẹfa ti mo ti ṣe sinima gbẹyin nitori gbogbo wọn ti pa mi ti. Wọn ti le mi nidi iṣẹ tiata tipẹ. Ko si ẹnikẹni to beere mi mọ. Nitori aisan yii ni gbogbo eeyan o ṣe bami sọrọ ninu iṣẹ tiata yii, pẹlu pe wọn mọ pe mo ti ta gbogbo ohùn ini mi, wọn da mi nu bi omi iṣanwọ lai beere mi wo rara.”

Ọdun to 2024 to kọja yii ni Halimah sọrọ jade pe aisan buruku kan tawọn oniṣegun ko tii ri koko kan nipa ẹ n ba oun finra. O ṣalaye bi aarẹ naa ti ṣe gbọn oun lowo danu to, ati bi o ti ṣe ba irisi ati ẹwa oun jẹ to. Ọpọ awọn ololufẹ rẹ ni wọn ba yọ pe aisan naa ko mu ẹmi ẹ lọ, bẹẹ lawọn kan sọ n pe ọrọ kobakungbe to sọ si Ojiṣẹ Ọlọrun to jẹ ololufẹ ẹ tẹlẹri, Apostle Johnson Suleiman, to ti fẹnu kọ, wọn leyii wa lara ohun to fa ipenija to doju kọ.

Ti ẹ o ba gbagbe, ni ọdun 2022 ni ija nla bẹ silẹ laaarin Apostle Suleiman ati Halimah bẹrẹ lori ẹrọ ayelujara nigba ti Halimah sọ faraye pe oun ati Ojiṣẹ Ọlọrun naa n ṣe wọle-wọde, eyi to si ti fa aisan si oun lara. O tun sọ pe aisan naa mu ki ẹjẹ bẹrẹ si i da lara oun, oyun to si bajẹ lara oun ko l’onka. Ọrọ yii bi Apostle Suleiman ninu gidigidi, o fesi pada pe irọ funfun balau Halimah pa, o si pinnu pe oun yoo kọ ọ lọgbọn, lo ba pe e lẹjọ si kootu, o si fẹsun ibanilorukọjẹ kan an, o ni kile-ẹjọ paṣẹ fun Halimah lati san owo itanran to to biliọnu kan Naira.

Abare-babọ, ile-ẹjọ paṣẹ ki Halimah ko ọrọ rẹ jẹ, ki o si san owo itanran miliọnu mẹwa Naira. Lẹyin eyi, ni Halimah jade lati tọrọ aforiji lọwọ Ojiṣẹ Ọlọrun naa. Ninu lẹta kan to kọ lasiko naa lo ti jẹwọ pe irọ ni oun pa mọ ọn, eyi si da awuyewuye rẹpẹtẹ silẹ lori ẹrọ ayelujara. Lọdun 2024 ni ẹgbẹ awọn oṣere tiata kan, Actors Guild of Nigeria pinnu lati fiya jẹ Halimah fun iwa ibanilorukọjẹ to hu, ni wọn ba jawee ‘ṣe tiẹ lọtọ fun un.’

Ṣa, ni bayii, irawọ oṣere-binrin yii n beere fun iranlọwọ awọn eeyan ja-n-kan ja-n-kan atawọn ẹlẹyinju aanu lawujọ lori ọrọ aarẹ rẹ yii. O loun ti kọwe ẹbẹ si gomina ati aṣofin kan nipinlẹ oun. O kadii ọrọ rẹ pe: “Mo nilo iranlọwọ bayii, o ti su mi. Mi o fẹẹ maa tọrọ owo kiri mọ!”

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search