Ọpọ ọkunrin Naija ko mọ bi wọn ṣe n dẹnu ifẹ kọ obinrin – Bukky Wright

Lati inu iriri rẹ, Bukky sọko ọrọ sawọn ọkunrin!

“Ki n sọ ododo ọrọ, keeyan lorukọ, keeyan jẹ ilumọ-ọn-ka maa n ṣakoba fun idile ẹni, o maa n nipa lori igbeyawo ẹni, ati pe ‘ṣe o tiẹ maa ri ọkunrin to nifẹẹ denudenu lati dẹnu ifẹ kọ ẹ ni?’ Irọ ni! Nitori lọpọ igba, awọn ọkunrin teeyan le ro pe ‘ẹni yii dẹ wu mi, o maa dara fun mi o,’ tabi tawọn naa n gbero lati dẹnu ifẹ kọ obinrin, lẹsẹ kannaa ni wọn tun maa n ro o pe ‘bawo ni kawọn ṣe sọrọ, ibo ni kawọn ti bẹrẹ.’

“Ọpọ igba ni mo ti wa niwaju ọkunrin to fẹẹ dẹnu ifẹ kọ mi, ti wọn aa dẹ maa sọ fun mi pe ‘awọn o tiẹ mọ ibi tawọn iba ti bẹrẹ,’ niṣe lẹnu maa n ya mi, ti maa fesi pe “ṣe loootọ? Ẹ bẹrẹ nibikibi to ba ti wu yin, o daa ẹ bẹrẹ lati ibẹrẹ, ọkunrin ni ẹ, obinrin ni mi. O yẹ ko ti ye ẹ!”

Ọrọ yii, atawọn ọrọ mi-in bẹẹ, lo n jade lẹnu irawọ oṣere-binrin onitiata to rẹwa bii egbin nni, Oluwabukọla Sẹkinat Ajọkẹ Wright, ti ọpọ eeyan mọ si Bukky Wright, ti wọn si tun maa n pe ni Ọmọtara Johnson, latari ipa to ko ninu fiimu olokiki rẹ kan, eyi to pe ni Ọmọtara Johnson lọdun diẹ sẹyin.

Nibi eto ifọrọwanilẹnuwo ori tẹlifiṣan Channels kan lọsẹ to kọja yii ni oṣere-binrin ti ọrọ da ṣaka lẹnu rẹ yii ti n fesi s’awọn ibeere ti wọn bi i, lede oyinbo. Nigba to n sọrọ lori bi jijẹ to jẹ gbajumọ oṣere ṣe nipa lori igbesi-aye rẹ ati ọrọ nini ẹnikeji, Bukky Wright ni, lọpọ igba, awọn ọkunrin ti wọn nigboya lati dẹnu ifẹ kọ oṣere-binrin to gbajumọ ki i ṣe iru ọkunrin ti wọn fẹ, o ni nitori owo, tabi okiki ti obinrin yẹn ti ni lawọn mi-in aa ṣe ranju mọ ati fẹ ẹ, ki i ṣe e pe wọn nifẹẹ rẹ denudenu.

O tun ṣalaye pe ọpọ igbeyawo to n fori ṣanpọn lagbo awọn oṣere tiata ilẹ wa, ki i ṣe ẹbi awọn oṣere-binrin o, o ni iru awọn ọkunrin to wa lode lasiko yii lo fa a, ti irinajo igbeyawo ki i fi tojọ tabi oṣu ki wọn too tuka. Eyi ni Iya-n-da’gbe baba-n-yọ-wa fi pọ laaarin awọn.

 

Ṣe Yooba bọ wọn ni, a ni kohun to wu’ni wa, ohun to dara lo yọju, bo ba dara amọ ti ko wu’ni n kọ? Bukky ni “koda, ti ọkunrin to nifẹẹ tootọ ba tiẹ yọju paapaa, ọpọ lara awọn ọkunrin atata bẹẹ le nifẹẹ loootọ, amọ wọn le ma mọ beeyan ṣe maa tọju obinrin to ti l’orukọ funra ẹ latilẹ wa, obinrin ti aye ẹ ti dara ki wọn too pade, wọn le ma mọ bi ajọgbe awọn mejeeji ṣe le wa pẹ titi, agaga nigba tobinrin naa ba tun lọọ jẹ oṣere tiata, wọn le bẹrẹ si i jowu buruku lori nnkan ti ko yẹ ki wọn jowu le lori, oni ẹjọ, ọla iregbe ni wọn maa ṣe titi ti igbeyawo aa fi daru.

Bayii ni Bukky Wright sọ o.

Odu ni Bukky Wright lagbo awọn oṣere tiata ilẹ wa, ọjọ aboki rẹ si ti pẹ ninu egungun daadaa. Lati aye ere ori itage, ko too di ti agbelewo lori fọran, lori ike mọnbe mọnbe ti wọn n pe ni CD tabi DVD, ati ti ori itakun ayelujara ti ẹrọ igbalode ode oni ni obinrin apọnbeporẹ yii ti n n fakọyọ. Lara awọn fiimu to ti kopa manigbagbe ni Ṣaworoidẹ, Agogo Eewọ, The Narrow Path, Ọmọtara Johnson, KKK – Kó’dùn, Kó’pọ̀, Kó’pẹ́, Abẹni Agbọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search