Aarẹ Yeye Oge tuntun, Laide Bakare dabira!

Laide Bakare joye Aarẹ Yeye Oge, o fi oge dabira

Pataki ni oge ṣiṣe jẹ nilẹ adulawọ, iran Yoruba ko si n fi ọrọ oge ṣiṣe ṣere. Idi niyi ti wọn fi maa n sọ pe Yoruba gbọ faari, nitori ipo iwaju ni wọn wa bo ba di ọrọ imura, itunraṣe, ṣiṣe ara lọjọ, yiyan fanda, dida gọjọgọjọ ati ipolowo ẹwa.

Ọkan pataki ninu awọn oṣere-binrin ilẹ wa ti ko kẹrẹ nidii oge ṣiṣe ni apọnbeporẹ onitiara nni, Laide Bakare. Ṣaaju ki awọn ikanni ajọlo bii instagiraamu ati fesibuuku tabi Tiktok too de ni arẹwa oṣere yii ti gbọ faari, ko kẹrẹ nibi aṣọ igbalode ati ti atijọ wiwọ, bo ṣe maa n gbeju gbere pẹlu ẹrin ẹyẹ, bẹẹ lo tun maa n fi ẹwa ati irisi rẹ ṣakọ. Eyi lo mu ki eekan onifuji nni, Wasiu Ayinde Mashal, ti wọn tun n pe ni KWAM 1, kọrin ki i lọdun diẹ sẹyin pe ‘Ọlaide sọ tiata d’owo.’

Lọsẹ to lọ lọhun, ninu oṣu Keji ọdun 2025 yii ni ọkan ninu awọn ori-ade ilẹ Yoruba, Timi ti ilẹ Ẹdẹ, fi oye Aarẹ Yeye Oge ti ilẹ Ẹdẹ da awẹlẹwa yii lọla. Gọngọ sọ lọjọ naa, pẹlu bi Laide Bakare ṣe ṣagbeyọ aṣa ati oge ninu aṣọ ofi ti wọn ran lọna ti igbalode to wọ. Ṣe sanyan ni baba aṣọ, alaari si ni baba ẹwu gẹgẹ bi Yoruba ti n sọ, bi Laide Bakare ṣe ro dẹdẹ to kan dudu, ti imura rẹ ṣalekun ẹwa rẹ fihan pe inu rẹ dun fun oye tuntun yii, ati pe oye naa ba a mu wẹku, obinrin naa gbọ nipa oge lọpọlọpọ.

Yatọ si imura oye, Laide tun wọ’ṣọ leesi funfun kinniwin kan, ti gbogbo rẹ ṣe rẹgi pẹlu ẹgba ọrun funfun ati ilẹkẹ ọwọ, oruka goolu to dọgba delẹ.
Ṣa, ni bayii, Laide ti kuro ni onitiata nikan o bo tilẹ jẹ pe ko tii fi iṣẹ ere itage ṣiṣe silẹ, bẹẹ lo ṣi wa ni ipo Oludamọran pataki lori ọrọ ariya ati aṣa si gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, amọ o ti di Aarẹ Yeye Oge ilẹ Ẹdẹ, obinrin alafẹ to gbọ faari nilẹ Yoruba!

ITAFAAJI naa n ki Laide kuu oriire. Oye aa mọri o!  

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search