IYAWO OLUWADORLAZ KỌ SI’LẸ, O TUN PARIWO Ẹ F’AYE

IYAWO OLUWADORLAZ NI ONI ṢINA AYE PARAKU NI

Sadede ni eefin ọrọ yii dede ru tuu si’ta nigba ti Adegoke Ifeoluwa to n jẹ Ife_Luv lori ayelujara to jẹ afẹsọna ati iya ọmọ gbajumọ agbe-fọnran alawada jade n ni, Olamide Ogunleye ti ọpọ Oluwadorlaz gba ori ikanni Instagram rẹ lọ lati fi igbe ta, to sin pantete ọrọ si’ta f’aye gbọ ni’pa bi iṣu ṣe ku ati bi ọbẹ ṣe bu laarin Oluwadorlaz ati afẹsọna rẹ Ifẹ_Luv to n na jẹ oṣere.

Ifẹ ni oun ko lee dakẹ ku ọ, eyi ti oun fi ọrọ naa ṣe amumọra bii iso inu ẹku nitori ọmọ to n bẹ laarin oun ati gbajumọ alawada naa  ti to gẹ ko to gb’odi patapata lara oun. O ni gbogbo oun to n ṣẹlẹ naa ti de gongo’ri ẹmi o oun.

Ninu alaye ti Ife-Luv ṣe lori ayelujara lo ti ni     

“kilode ti awọn eniyan daju bi alailẹri ọkan rara. L’ọpọ igba, a maa ṣe mi ni kayefi wi pe kilode ti ọkan ẹda kun fun oro ati iwa ibi. Mo mọ wipe o ṣeeṣe ki oluranlọwọ-aba’ni-tẹ-ọrọ-safẹfẹ (handler) o fa ọrọ yii yọ kuro loju opo, amọ ṣa mo n la oun to le pupọ kọja, ti ko si rọrun fun mi rara. Mo n koju iwa ọdale nla kan lọwọ  bayii, ti mo si ṣẹṣẹ bọ kuro ninu iṣẹ-abi. Ki okunrin kan o si wo mi loju sunsun pa irọ oju-koroju fun mi laib’eṣu-bẹ’gba. O nira pupọ fun mi tori mo si tun gbọdọ jẹ iya rere. O n ṣe mi bi kin bu s’ẹkun gbaragada, a mọ ṣa ti mo n fi akọ ẹrin gbe tori ọmọ mi ọkunrin. Ọrọ yii ba mi pupọ ju, ti n o si ja pẹlu gbogbo eemi inu mi. Mo mọ wipe lootọ aye le, emi naa ko si pe tan, a mọ ṣa iru eyii ko tọ si mi rara.”

Obinrin yii ko fi mọ ni’bẹ o, n ṣe lo tun fi ọkan to gb’ọgbẹ ọkan tu aṣiri gbogbo ohun ti oun ati Oluwadolarz jọ se ti ile o fi n jo’na lasiko yii si’ta. A  fi bii pe eeyan fọ’gba yanga.

Ẹ o ranti pe l’oṣu kejila odun 2023 ni iroyin gbe wipe Oluwadorlaz bẹ iyawo rẹ lori ọrọ aṣemaṣe. Nibẹ gan ni Ife-Luv ti mu ọrọ lasiko yi. O ni odidi ọdun meji gbako ni Oluwadolarz fi bẹ oun wipe o ti yipada nigba ti oun kọkọ jaa ju silẹ l’akọkọ nitori iwa agbere ti Oluwadorlaz n hu to si jẹ pe oun ni oun gbe eyi to pọ jù ninu ẹru bukata itọju ọmọ awọn tori owo ki ṣaba si to bẹẹ l’ọwọ Oluwadorlaz tọ bẹẹ l’ọpọ igba, pe lẹyin ko dibọn bi pe aye rẹ bẹsuẹ, ko si ṣe agbere gẹgẹ bi oloju-komu-o-lọ, ko ni ohun miran to fi aye rẹ jin fun. “Ko ni ga, ko ni go, gbogbo igba ni awọn ile-iṣẹ to n baa dowopọ a maa ṣ’aroye wipe iṣẹ rẹ ko mu yanyan to.” O ni afi ki o maa f’apa bo ba rii wipe oun ṣe daada, bẹẹ kẹ owo si n bẹ l’ọwọ t’oun.

Síwaju si oṣere’binrin yii ni n ṣe ni Oluwadorlaz yoo maa ṣe’ke wipe oun ti pa iwa da, amọ ṣa ti aguntan rẹ ko pa aṣọ eṣi da oun ko si tete mọ tori awọn ko gbe papọ, ti kii sii ṣe gbogbo igba ni oun ma n waa lọ. O ni ohun to wa kuku fọ igba yanga ni bi oun ṣe lọ si ọdọ rẹ lati lọ mu ọmọ wọn okunrin, amọ ṣa ti oun ri imu he ti ete si sọnu lagbari ohun pẹlu bii oun ṣe ba ọmọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Lọla to jẹ ọkan lara awọn oṣere fun Oluwadolarz to f’arapamọ f’oun sinu baluwe, ti ọmọ oun si wa ninu ile naa. A mọ ṣa ti baba ọmọ oun ko b’eṣu bẹ’gba lati pa irọ oju-koroju fun oun, ṣugbọn ti oun ti ri gbọ l’adugbo wipe o sunmọ ki Lọla ti yọ oyun fun Oluwadorlaz lai mọye igba s’ẹyin. To si tun ni bii ọkunrin alawada naa ti maa n nawọ fifẹ si gbogbo awọn oṣere’binrin to ba n ṣiṣẹ pẹluu rẹ.

Ife-Luv tun tẹsiwaju lati sọ asọyan wipe oun kii ṣe ọkan l’ara awọn serekode rẹ o, amọ ṣa ti Oluwadolarz jẹ ọkunrin akọ’fẹ oun. Ni ipari o ni oun ko ri ti wọn ro to nkan tori oun ṣe la iṣẹ-abẹ kọja ni. A mọ ṣa ti okun ifẹ oun ati Oluwadolarz ti rẹ ja patapata bayii.

Lati ṣ’ami wipe oun ti gbọnran jigi kuro nibi iṣẹlẹ naa ti Oluwadolarz si ti di itan ninu igbesiaye rẹ, bii Ifẹ-Luv ti n tẹ ọrọ jiṣẹ lori ayelujara lo tun fi awọn aworan to n paroko ransẹ. Lara wọn ni ibi to ti wa ni ile if’aranisinmi (vacation).

Orisirisi ọrọ ati ero lo kun inu awile Ifẹ_Luv, bi awọn kan ti n ki pe o s’ọrọ s’oke, l’awọn kan n ni iru obinrin daada bayi ko yẹ Oluwadolarz wipe iru iyawo Landẹ lo yẹ ko ri”. Ọrọ pọ o, amọ ṣa kini ero yin lori iroyin yii? Ẹ bun wa gbọ ninu apoti awile.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search