O ni ko yẹ ko ya'ni l'ẹnu rara wipe awọn obinrin kan n fi ara wọn dii lati lee di irawọ oṣere
Botilẹjẹpe ojumọ kan ara kan nani tẹlẹ lagbo awọn amuludun, paapa julọ laarin awọn oṣere tiata, a mọ ṣa gbankọgbi l’eyi tun jẹ nigba ti agba oṣere kan, ọmọba Jide Kosoko ṣe f’ọgba yanga lori eto onigbadegba kan lori I amohunmaworan ati ayelujara lorii bi awọn oṣere’binrin kọkan ṣe n m’ẹyin le’lẹ lati lee di irawọ oṣere lẹka ere agbelewo.
Jide Kosoko lori eto naa fi ẹnu kun orisirisi awọn iṣẹlẹ laarin ilu, to si fi ero rẹ han. A mọ ṣa lara eyi ti aye gbamu ti wọn si n kọ bi orin laarin ilu ni bi agba oṣere naa ṣe ni alalanlala, ẹran ki laa jẹ ri. O ni ko yẹ ko ya’ni l’ẹnu rara wipe awọn obinrin kan n fi ara wọn dii lati lee di irawọ oṣere, o ni koda oun mọ awọn miran ninu wọn ti wọn ti da iru aṣa yii s’ẹyin ti wọn si jẹ gbajumọ t’aye n p’okiki rẹ lonii.
Agba oṣere yii to tun ni awọn ọmọ olokiki ni’di iṣẹ tiata tun tẹsiwaju wipe, lati ayeb’aye ni aṣa yii ti n bẹ ti kii sii ṣe laarin awọn oṣere nikan ati wipe kii ṣe on to le to bii awọn kan ṣe maa n mu laarin ilu.
O ṣalaye wipe botilẹjẹpe lootọ ni wipe awọn agbesinima ja’de ati adari ere kọkan a maa nawọ gbigbọ iṣẹ ara ẹni si awọn osere’binrin kọkan pẹluu ireti ati sọ wọn di olokiki ni’di oṣẹ ere, amọ ṣa, Jide Kosoko ṣalaye wipe wọfun ni itẹlọrun lorii ọrọ naa, ipa o ra’ja bẹẹ ni ipa o si taa pẹluu bo ṣe jẹ pe o ku s’ọwọ oṣere’bin ti wọn ba na’wọ anti ẹ m’ẹyin wa si lati jẹ hoo abi ko kọ ja’lẹ ti kosi ni wahala abi ifipa mu’ni ninu rara.
Jide Kosoko m’ẹnu l’ọrọ de’bi wipe awọn oṣere’binrin kọọkan to n fẹ lati di irawọ oṣere a maa wa anfani ati j’ọwọ ara wọn fun awọn ti wọn ba gbagbọ wipe wọn lee sọ wọn di olokiki, ṣe aṣa kan a maa lọ bayii wipe ohun ti a ba ni lao fi wa ohun ti a n fẹ ti a ko ni. O ni bi ọrọ fifẹ abi ibalopọ ba wa’ye, ọrọ awọn meji tan nilo ara wọn lo wọ nuu ti ko si gbun ẹnikẹni to ri ogun to ti jẹ bi idan ni fun awọn oṣere’binrin kan to ti di gbajumọ l’ode oni. Bẹẹ lo tun tọ’ka wipe oun tun mọ adajọ ile-ẹjọ majisireeti kan t’oun naa ti fi abẹ l’ana fun ara rẹ, fun idi eyi ko jẹ tuntun, ko si mọ laarin awọn amuludun nikan.