TỌPẸ ALABI ATI LIZZY ANJỌRIN YẸYẸ ARA WỌN NI GBANGBA

kini o fa idarudapọ larin awon gbajumo meji yii?

Yooba bọ, wọn ni abamọ ki i ṣaaju ọrọ. Ọrọ yii lo wọ ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii laaarin awọn ololufẹ ilumọ-ọn-ka oṣere-binrin onitiata tọrọ da lẹnu rẹ daadaa nni, Elizabeth Anjọrin, tawọn eeyan tun n pe ni Lizzy Anjọrin, ati gbajugbaju akọrin ẹmi lobinrin nni, Abilekọ Tọpẹ Alabi, ti isọko ọrọ sini fi waye laaarin wọn, debi ti ọrọ aawọ ọhun fi di eyi tawọn olufẹ awọn oṣere mejeeji yii n ṣe fa-n-fa le lori, agaga lori ẹrọ ayelujara.

Bawọn kan ṣe n sọ pe iwa abuku ati igberaga patapata gbaa ni Tọpẹ hu, ti wọn n ni ojiṣẹ Ọlọrun kan ko gbọdọ ṣeru nnkan bẹẹ si awọn ololufẹ rẹ, bẹẹ lawọn mi-in n di ẹbi ru Lizzy atawọn ololufẹ rẹ, wọn lo yẹ ki wọn ti ṣe nnkan kan ṣaaju ki iṣẹlẹ yii to waye.

Ṣebi Lizzy ni ọjọọbi rẹ ko, lọjọ kẹrin oṣu kẹrin ọdun 2025 yii, ayajọ ọjọ ọhun lo si maa n ṣe baidee rẹ lọdọọdun, o si ti di aṣa awọn kan lati ṣe nnkan iyanu ati ijọniloju fun ọmọ ọlọjọọbi ti wọn fẹran, paapaa lagbo awọn irawọ oṣere ti wọn lero lẹyin. Lọpọ igba, awọn ọrẹ ati ojulumọ maa n ṣe sọpuraisi baidee fun ẹni wọn, iyẹn ni pe lai fu ọlọjọọbi lara, wọn le ṣadeede ji ka a mọle lọjọ naa, ki wọn si bẹrẹ si i kọrin ọpẹ ati iyin, ki wọn maa pokiki rẹ, wọn si tun le fi ẹbun ta a lọrẹ. Eyi maa n mu ori ọlọjọọbi wu nitori ko nii reti iru nnkan bẹẹ, yoo ba a lojiji, yoo si jọ ọ loju jọjọ.  

Iru ayẹyẹ baidee iyanu bẹẹ lawọn ọrẹ ati ololofẹ Lizzy Anjọrin ti gbero rẹ labẹnu, wọn si pinnu lati fi pe Tọpẹ Alabi lawọn yoo pe lati fi orin iyin ati ọpẹ kanlẹkun ile Lizzy laaarọ ọjọọbi rẹ. Wọn ti ba Tọpẹ sọrọ, wọn si ti fun un lowo to loun maa gba, gbogbo eto yooku ni wọn ti pari, wọn si ti da akoko fun ara wọn ati ibi ti wọn yoo ti pade, amọ gbogbo eto yii, bookẹlẹ patapata ni, ọrọ mọ-sinu-mọ-sikun ni wọn fi ṣe, nitori wọn ko fẹ ki olobo kankan ta Lizzy ṣaaju ọjọ naa, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe e. O jọ pe nibi ti wọn bo kinni ọhun laṣiiri de, wọn ko jẹ ki Tọpẹ mọ pe ọdọ Lizzy ni yoo ti lọọ kọrin lafẹmọjumọ ọjọ Ẹti, Furaidee ọjọ kẹrin ọhun, wọn kan sọ fun un pe ọkan lara wọn ololufẹ rẹ gidi, ati irawọ oṣere-binrin kan lawọn fẹẹ fi kinni naa ṣe ayọ ojiji fun ni.

Amọ ọrọ bẹyin yọ, nigba ti Tọpẹ Alabi de ibi ti wọn ti fẹẹ ko kọrin ọpẹ fọlọjọọbi, to jẹ pe bi Tọpẹ ṣe mọ pe ṣọọbu itaja Lizzy Anjọrin to wa lagbegbe kan niluu Ikorodu nipinlẹ Eko llawọn n bọ, Lizzy loun fẹẹ kọrin fun, niṣe lo  kọ jalẹ lati ṣere nibi ayẹyẹ ọjọ-ibi naa, ti ko si tun beṣu bẹgba lati da owo ere to ti gba pada, pẹlu ibinu lo fi kuro nibi ariya naa ni kiamọsa, eyi si ya ọpọ eeyan to wa nibẹ lẹnu, koda o bomi tutu si wọn lọkan pẹlu, wọn n ṣe kayeefi lori ohun ti Tọpẹ ṣe yii, ati bo ṣe ja wọn ni tanmọ lojiji. .

Lọgan ti awo iṣẹlẹ yii ti lu sita lo ti da awuyewuye ati họwu-họwu nla silẹ laaarin igboro ati lori ẹrọ ayelujara. Ọkan pataki lara awọn to ti fi ẹnu kun iṣẹlẹ yii ni Ọgbẹni Ooreọfẹ Williams ti awọn miiran tun mọ si Awojesu to jẹ agbe-sinima-jade ati olukọni nipa iṣẹ tiata, wọn lọkunrin yii naa lo ṣe atọna bi wọn ti ṣe pe Tọpẹ Alabi sibi ayẹyẹ ọjọ-ibi naa.

Ninu alaye ti Ọgbẹni Ooreọfẹ ṣe, o ni ọsẹ diẹ ṣaaju ọjọ ayẹyẹ yii ni agbe-sinima-jade kan kan si Tọpẹ Alabi lati wa kọ’rin l’ode ariya oun,  pẹluu alaye wipe oun n gb’ero lati ya ẹnikan to ṣe iyebiye pupọ si oun l’ẹnu ni. Amọ ti ẹni to jẹ ni pato ko f’oju han lasiko gbogbo idunadura wọn.

Ooreọfẹ tun ṣalaye siwaju si i pe latari bo ṣe jẹ po oun loun ṣe alatọna wọn, Tọpẹ Alabi di awọn ololufẹ Lizzy ọhun lowo, iye to yẹ ko ṣaaji taara fun irufẹ ode ariya bẹẹ kọ lo gba lọwọ wọn, dipo miliọnu mẹta aabọ to yẹ ko gba, milịọnu meji aabọ lo gba, bo tilẹ jẹ pe o ti da owo naa pada nigba to pinnu lati maṣe kọrin ọhun mọ.

Lọgan ti olorin ẹmi yii ati ikọ rẹ de si ibudo ayẹyẹ naa ti wọn si kẹfin wipe Lizzy Anjọrin lo n ṣe ọjọ-ibi n lo kuro nibi ode naa gẹgẹ bi alaye ti Ọgbẹni Sọji Alabi to jẹ ọkọ Tọpẹ Alabi ṣe. O lohun to mu kawọn kuro nibẹ ni pe awọn kẹfin iwa agabagebe ati aiṣotitọ pẹlu bi wọn ṣe fi bo ti awọn ko si mọ titi di asiko wiwọ inu ibudo naa, pe oṣere’binrin Lizzy Anjọrin lo n ṣe ayẹyẹ ọjọ-ibi.

Awojesu funra rẹ naa wa n ṣe eemọ lori pe ki lo le faa ti awọn oni nkan yoo ṣe fi orukọ ọlọjọ-ibi pamọ fun elere gẹgẹ bi oun to ṣe’ni ni kayefi pupọ leyii to ṣokunfa bi Tọpẹ Alabi ko ṣe wulẹ bọ si’lẹ lati inu ọkọ ti o gbe wa.

Ṣe ba a ba fa gburu, gburu a f’agbọ. Lẹgbẹ kan ni tiẹ, Lizzy  Anjọrin ti f’esi pada si gbogbo awuyewuye aroye ọtẹ to n lọ l’ọwọ, o ni oun o le fi owo oun pe Tọpẹ Alabi wa kọrin fun oun, dipo bẹ oun a ya pe awọn akewi abi awọn olorin miran. Ko tan sibẹ, Lizzy tun mẹnuba bi awodi oun ṣe ba Tọpẹ Alabi ra lasiko to n koju ifinamọ.

Titi di asiko kiko iroyin yii jọ, alaye taara lati akata Tọpẹ Alabi ko tii ja’de, amọ ọrọ yii ṣi n gbona gidigidi laarin igboro.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search