Bi ki i ba ṣe pe oge ṣiṣe ti wa ninu ede Yoruba latọjọ pipẹ ni, niṣe leeyan iba ro pe Iyabọ Ojo, ọmọ rẹ, Priscila ati ọkọọyawo tuntun ara Tanzania to fẹẹ fẹ ọmọbinrin ọhun, Juma Jux, lo kọkọ pilẹ oge ṣiṣe ni, pẹlu bi ori ẹrọ ayelujara ṣe n ho ṣọṣọ fun oriṣiiriṣii ara, oriṣiiriṣii fọto, imura, iwọṣọ ati fidi ẹwa ṣakọ gẹgẹ bii apakan ipalẹmọ fun igbeyawo alarinrin to wọle de tan ọhun.
Priscilla ati ololufẹ rẹ, Juma Jux n ṣere oge
Ni bayii, o jọ pe gbogbo eto ti pari, ọlọjọ n ka ọjọ lo ku, pẹlu bo ṣe ku ọjọ mẹrin pere ti gbẹgẹdo yoo gbina, ti pẹpẹyẹ yoo gbọmọ pọn nibi ayẹyẹ igbeyawo alarede Priscila Ojo ati ọkọ rẹ.
Ṣe iyawo dun lọṣingin, bi Yoruba ti n wi, lori ikanni Instagiraamu wọn, ojumọ kan ara kan, ojumọ kan oge ọtun ni, pẹlu bi tọkọtaya naa ṣe n fi ifẹ han si ara wọn ninu aṣọ alarabara ti wọn n wọ, ti toni ko si jọ tana, bẹẹ bi awọn mejeeji ṣe n ṣe tiwọn, naa ni Iya Iyawo tuntun yii, Iyabọ Ojo ko gbẹyin, gbogbo ipalẹmọ, lilọ bibọ rẹ lori bi ayẹyẹ ọjọ naa yoo ṣe kogo ja, ti yoo dun ti yoo larinrin, irin ẹwa ati oge lo n fi gbogbo rẹ ṣe.
Lọjọ Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin yii, ati ọjọ Sannde to tẹle e, Priscila ati ọkọ rẹ gbe awọn fọto to jojunigbese kan bayii, ti wọn diidi ya lati polongo ifẹ wọn faye gbọ ati lati ran awọn ololufẹ wọn gbogbo leti pe ọjọ ti wọn ti n reti naa ti n kanlẹkun, ki gbogbo ẹni to ba fẹẹ ganu si i tete maa gbaradi bayii.
Ẹ o ranti pe ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni Iyabọ Ojo ti lọọ ṣabẹwo si Ọọniriṣa, Ọba Adeyẹye Ẹniitan Ogunwusi, o mu iwe ikesini lọọ fun ori-ade naa lati fidi rẹ mulẹ pe Ọọni ni Ọba awọn ọba ti yoo gunwa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọhun.
Ka ma purọ, igbeyawo ara-ọtọ ni Iyabọ Ojo n mura fun ọmọ rẹ, onipele ipele si ni, tori ṣaaju asiko yii ni obinrin naa ti ṣeleri pe aye aa gbọ ọrun yoo si mọ pe ẹni nla n ṣe nnkan nla lọjọ ayẹyẹ naa.
Lati oṣu diẹ sẹyin ni igbeyawo ati idana kan ti waye lorileede Tanzania, nibi ti wọn ti oṣere tiata kan ti tẹle Iya iyawo yii ati ọmọ rẹ lọọ ọdọ awọn mọlẹbi ọkọ ọmọ ọhun, ti wọn si gba wọn lalejo tọwọ tẹsẹ.Adura tawọn ololufẹ Iyabọ n ṣe fun un bayii ni pe Ọlọrun yoo ba mu ọjọ ro, iṣe rere ọmọ rẹ ti n ṣoju rẹ bayii na, wọn ni adun ati oyin ni yoo gbẹyin ayẹyẹ wọn to de tan yii.