Nitori igbeyawo Priscilla, Iyabọ Ojo ko si pampẹ EFCC

Owe Yoruba kan ni bi ori ba ṣe tobi to lo ṣe n fọ olori, owe yii lo wọ ọrọ ayẹyẹ igbeyawo Priscilla Ojo, ọmọ eekan oṣere-binrin tiata ilẹ wa to gbajumọ lori ẹrọ ayelujara nni, Iyabọ Ojo.

Priscilla ati ọkọ rẹ pẹlu Iyabọ Ojo

Ọpọlọpọ ọrọ ati awuyewuye lo ti jade lori ayẹyẹ nla tokiki rẹ kari aye naa, titi dasiko yii ṣi ni ọrọ nlọ lori pati naa,

 amọ tuntun to yi wọ ọ ni pe ajọ EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti aṣa ṣiṣe ṣiṣe owo baṣubaṣu ati iwa ajẹbanu gbogbo, Economic and Financial Crimes Commission, ti kọwe pe Iyabọ Ojo lati foju kan wọn lọfiisi wọn, wọn ni ko waa ṣalaye fawọn, awọn lawọn ni awọn ibeere pataki kan lati bi i, awọn fọran fidio kan si jade lati pati ti wọn file pọnti fọna roka rẹ yii, to gbọdọ sọ bo ṣe jẹ gan-an fawọn,

ki wọn le mọ igbesẹ ofin ti wọn maa gbe lori rẹ, obinrin naa si ti lọọ jẹ wọn.

Ṣe ko kuku sẹni ti ko mọ pe lasiko yii, bawọn mẹkunnu ṣe nifẹẹ si pati olowo lati ri ọwọ pọnla, bẹẹ nijọba Naijiria, paapaa julọ, ajọ EFCC naa n gẹgun, wọn n ṣọ gbogbo ohun to n lọ loju agbo, wọn wo awọn afowo dabira, awọn nawo-nawo ti o mọ ila towo kọ, atawọn to n bu naira bii ẹwa ọṣọṣọ gbogbo.

Ṣe ko sẹni tọrọ dun lẹnu rẹ bii ‘o ṣoju mi koro’, Iyabọ Ojo funra rẹ lo boode ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2025 yii, lati tan imọlẹ si irin-ajo rẹ lọ si ọfiisi awọn EFCC n’Ikoyi, l’Ekoo.

Loju opo Instagiraamu rẹ ni arẹwa oṣere tọrọ da ṣaṣa lẹnu rẹ yii gba lọ lọjọ Tusidee, o ni ọgọọrọ eeyan ti wọn gbọ nipa ikesini EFCC ati boun ṣe lọ sọfiisi wọn ni wọn ti n ko ọkan soke, ti wọn wọn n fẹẹ mọ ohun to ṣẹlẹ, bi atẹjiṣẹ ṣe n kọlu ara wọn lori foonu oun, bẹẹ ni ipe n ja lu ara wọn, latọdọ awọn ololufẹ oun nilẹ yii ati lẹyin odi, idi si ree toun fi fẹẹ ṣalaye bọrọ ọhun ṣe lọ.

Iyabo Ojo

“Lẹyin eyi lawọn EFCC fi fidio kan han mi, o ṣafihan apakan awọn nnkan to waye nibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ mi, nibi tawọn alejo atawọn ọrẹ ti n ṣariya, ti wọn n fọn owo, owo Naira ilẹ wa atawọn owo ilẹ okeere bii dọla ati pọun.

Iyabọ Ojo tẹnu bọrọ, o ni: “Ilu oyinbo, ni United Kingdom ni mo wa nigba ti wọn mu lẹta EFCC wa sile mi l’Ekoo, pe wọn fẹẹ ri mi lọfiisi wọn. Bi mo ṣe dari de, mo lọ sọfiisi wọn lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2025 yii, wọn si da ọpọ ibeere bo mi, bẹrẹ latori ẹni ti mo jẹ, ọjọ ori mi, iṣẹ ti mo n ṣe, iriri mi lẹnu iṣẹ, awọn ileeṣẹ ti mo ni, ati gbogbo nnkan bẹẹ bẹẹ.

Juma Jux ati iyawo rẹ, Priscilla

 

Wọn bi mi leere boya mo mọ pe aṣa yii lodi sofin ilẹ wa, mo si fesi pe owo Naira nikan lemi ro pe teeyan ba ṣe e baṣubaṣu, o lodi sofin.

 

 

“Awọn oṣiṣẹ EFCC naa waa la mi lọyẹ pe aṣa fifọn owo, titi kan lilẹ owo mọ ẹlomi-in lori tabi lara, tako ofin, gbogbo owo leyi si kan, ibaa jẹ owo dọla. Eyi ya mi lẹnu diẹ o.

“Lẹyin ti mo ti dahun awọn ibeere wọn, wọn fi mi silẹ ki n maa lọ lọjọ yẹn, amọ lọọya mi, Amofin O. I. Salami lo ṣe oniduuro fun mi, tori wọn ni igbakuugba lawọn tun le pe mi lori ọrọ yii.

Iyabo ati tọkọtaya tuntutn

“Pẹlu ohun to ṣẹlẹ yii, mo fẹẹ ṣekilọ gidigidi fun gbogbo eeyan pe ki wọn yẹra fun fifọn owo eyikeyii ni pati o, ti wọn o ba ti fẹẹ ko si pampẹ EFCC.

“Boya o ti n to akoko lati wo aṣa lilẹ owo mọ elere ati oninaawo lori, eyi to ti mọ wa lara to si ti wa tipẹ nilẹ yii. Ẹ jẹ ka tun ero wa pa, ka si ṣọra o, ka maa ba ko si wahala.

“Ẹ ṣeun o.”

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search