Ẹsẹ orin kan ti ogbontarigi onijuju nni, Oloye Ebenezer Obey, kọ ninu awo rẹ kan lo lọ bayii pe: “Awa ọkunrin le laya meji, ko buru, ọkunrin kan-ṣo lọba Oluwa mi yan fobinrin,” eyi si fidi rẹ mulẹ pe eewọ ni fun obinrin lati wa nile ọkọ meji lẹẹkan naa, amọ ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii o, obinrin kan ti n fẹ ọkọ meji l’ode iwoyi, eyi si ni ẹsun to gbe Abilekọ kan, Hajiya Harira Tundun Murtala de ile-ẹjọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un ta a wa yii, nipinlẹ Kano.
Bii awada kẹrikẹri ni ọrọ naa kọkọ jọ nigba ti igbẹjọ bẹrẹ niwaju Onidaajọ Khadi Munzali Tanko Soron-Dinki ti ile-ẹjọ Sharia kan to fikalẹ si agbegbe Post Office Area, nigboro ilu Kano, nipinlẹ ọhun, niṣe lawọn eeyan to wa ni kootu kọkọ ku sẹrin-in, nigba ti wọn ka ẹsun ti wọn fi kan Hajiya Harira jade pe o lọkọ meji lẹẹkan naa lo ṣe dero ile-ẹjọ.
niṣe Iyawo lọọdẹ ọkọ yii wolẹ ṣun-un, to si fesi pe, ‘Loootọ ni, Oluwa mi’.
Gẹgẹ ọpọ eeyan ṣe reti, obinrin naa kọkọ sẹ kanlẹ pe oun ko jẹbi ẹsun ọhun, o ni ‘ki Oluwa mi maṣe da wọn lohun, irọ ni wọn pa mọ oun’, amọ ọrọ rẹ yi pada, iyalẹnu patapata lo si jẹ nigba ti adajọ paṣẹ pe ki olujẹjọ yii fi Kurani bura, ko si dahun ibeere oun.
Lẹyin ti wọn bura fun un tan, ti adajọ tun beere lọwọ rẹ pe ṣe loootọ lo ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin meji lasiko kan naa, niṣe Iyawo lọọdẹ ọkọ yii wolẹ ṣun un, to si fesi pe, ‘Loootọ ni, Oluwa mi’.
Ninu alaye tawọn agbẹjọro olupẹjọ ṣe, wọn ni Ọgbẹni Sagiru Shuaibu Murtala lo kọkọ fẹ Hajiya Tundun, o sanwo ori ẹ, wọn si ṣegbeyawo alarinrin, leyii ti ko tii ju oṣu mẹfa sẹyin lọ. Amọ tọkọtaya naa ko jọ gbe ile papọ, niṣe ni ọkọ gba ile fun un, to si maa n lọọ ṣe baale ile lọdọ rẹ nigbakuugba ti orun ba ti kan an.
Wọn ni aipẹ yii ni Ọkọọyawo yii ṣabẹwo sọdọ iyawo ọṣingin rẹ yii, lo jẹ ọkunrin mi-in lo ba lọdọ rẹ, bo si ṣe fẹẹ pariwo le e lori pe ọwọ oun ti tẹ ale iyawo oun, lọkunrin naa, Ọgbẹni Bello Abdullahi Yankaba, gboju agan soke pe ‘oun kii ṣe ale o, ale bii ti bawo, ọkọ loun, oun loun fẹ iyawo, ọdọ aya oun loun si wa yii.’ Eyi lo mu ki ọrọ de kootu Sharia.
Nigba ti ọkọọyawo keji n ṣalaye ara rẹ niwaju adajọ, Ọgbẹni Bello ni oun fẹ obinrin naa niṣu lọka ni o, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) ni ẹgbọn rẹ, Ọgbẹni Abdullahi Umar, to duro gẹgẹ bii baba fun un gba lọwọ oun, tawọn si fẹra, ko si sọ foun pe ile-ọkọ kan loun wa rara, atigba naa loun si ti n ṣe ojuṣe oun lọsan loru, gẹgẹ bii baale ile rere.
Ki la o wa ti ṣeyi si? Nigba ti Adajọ Soron-Dinki wo sọtun-un sosi lọri ọrọ yii, o paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọọ tubọ ṣewadii kunnakunna si i lori ẹjọ ọhun, lati le fidi ododo mulẹ, o si ni ki wọn taari obinrin ọlọkọ meji yii si ahamọ na, titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.
Ibeere kan tawọn eeyan n beere bayii ni pe bi oyun ba ti duro si obinrin yii lara, ta a ni yoo ni ọmọ naa ninu awọn baba mejeeji ti wọn n ṣe ọkọ rẹ. Ki lẹyin ro?