Owe Yoruba kan ni ‘ọmọ ọsàn ni i kó póḿpó ba iya rẹ, ati pe Olúbọ̀bọ̀tiribọ̀: ẹnu l’ẹbọ! Afaimọ ni ẹnu ko ti ṣakoba fun ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Ojiṣẹ Oluwa yii o, nitori ni gbogbo ori ikanni ti orukọ rẹ ati iran to loun ri ti n jade lasiko yii, kóńgò èpè ràbàǹdẹ̀ ràbàǹdẹ̀ lawọn eeyan n ṣẹ fun un, ti wọn si n bú u ni mẹsan-an mẹwaa.
Iran buruku kan ti Pasitọ to n ṣiṣẹ ariran yii, ti wọn pe orukọ rẹ ni Aarẹ Karma tabi Karma President lede eebo lo fa gbogbo ibinu tawọn eeyan fi n juko ọrọ ati eebu si i.
Ariran Karma President, to fi orileede Ghana ṣe ibujokoo nibi to ti n sọ asọtẹlẹ, to si n riran fawọn eeyan, lo ṣadeede jiṣẹ kan to ni Oluwa fi han oun nipa gbajugbaja onkọrin hipọọpu taye n fẹ nni, David Adeleke, tawọn ololufẹ rẹ tun n pe ni Davido, tabi OBO, Ọmọ Baba Olowo ati Iyawo rẹ arẹwa, Chioma, ọlọwọọ-ṣibi.
Ariran yii ni gẹgẹ bi Oluwa ṣe fi han oun, toun ko si ni i fi ọkan pe meji, o ni igbeyawo Davido ati Chioma ti tuka tan o, o lawọn mejeeji maa ba ara wọn ja gidi, ko si nii si ẹni ti yoo ri i yanju, ajatuka n ni tagbaarin lọrọ wọn yoo da laipẹ yii.
O fi kun un pe lati ilẹ ẹmi ni igbeyawo naa ti n daru bọ, ati pe ọgọọrọ awọn iṣẹlẹ abẹnu kan to waye lo ṣokunfa ituka wọn, gẹgẹ boun ṣe n ri i.
Ojiṣẹ Oluwa yii ni afi ki Chioma tete wọle adura o, adura gidigidi ni, o si tun gbọdọ gbe adura rẹ gba ti ọna ibilẹ, aijẹ bẹẹ, mo ti fẹ Davido ri lọrọ rẹ yoo da, gẹgẹ bi ẹmi ṣe n fi han oun.
Afi bii ẹni pe awọn eeyan ko gbọ iru asọtẹlẹ bẹẹ ri, niṣe lawọn ololufẹ Davido ati Chioma gba fi ya Ariran Karma Purẹsidẹnti yii, ti wọn bẹrẹ si i sọrọ lile si i loriṣiiriṣii.
Ugo ni, abi ẹ o maa gbọ Aririan aburu, oo ṣe kọkọ riran sawọn tọkọtaya ti wọn n kọ ara wọn silẹ ni Ghana na?
Monica ni: Ọlọrun aa daabo bo Davido ati Iyawo rẹ o, yoo si fepe fun elepe dandan. Enoch ni: Igbeyawo tiẹ ati ti baba ẹ lo maa fori ṣanpọn, iwọ ariran jatijati yii.
Ẹnikan tun sọ pe: Ti wọn o ba tii maa fi ọlọpaa gbe awọn ariran radarada wọnyi, wọn o nii kọgbọn. Iru Ojiṣẹ Eṣu wo lo n pe ara ẹ ni Ojiṣẹ Ọlọrun yii na? Ati bẹẹ bẹẹ lọ.