O TO GẸ, OWO AṢỌ-ẸBI TI FẸ PA MI! – OṢERE, BIỌLA ADEBAYỌ PARIWO

Yatọ si inu ere agbelewo ati fọnran ranpẹ (skit), ibi pataki ti awọn oṣere tun ti ma n wa l’oju t’aye ni ode ariya ti ọpọ mọ si ‘owanbẹ’ l’asiko yii. O lee jẹ igbeyawo, ọjọ-ibi, oku agba, iṣile, ajọdun iṣẹ abi ayẹyẹ isafihan sinima tuntun iyẹn ‘premier’.

Awọn owanbẹ yii kii wa bẹẹ lasan. Anfani pataki ni fun awọn ilumọọka l’awujọ lati yọ’ra f’aye t’ori ti wọn mọ pe oju gbogbo lo wa lara wọn. Awọn aṣọ ati ẹṣọ ara a-wo-da’mi-enu, awọn ọkọ a-wo-ṣi-fila olowo iyebiye. Koda, wọn a tun ma fi ọla taka laarin awọn ti ọpọ ololufẹ naa si kundun eyii, pẹlu ifojusọna fun owanbẹ tuntun lẹyin ọkan. Ọbẹ to si dun, owo lo pa, ẹgbẹlegbẹ miliọnu ni awọn ilumọọka fi n ṣe abaṣe ati karimi loorekoore.

Iru ọbẹ eyi gan-an lo dabi ẹni pe o ti n jo arẹwa oṣere’birin nni, Biọla Adebayọ l’ẹnu. N ṣe ni obirin yii ke gbajare l’ori ayelujara pe, awọn pati (party) yii ti fẹ pọju f’oun. O ni, ni fẹrẹnjogi to ku ninu ọdun 2025 yii, ko din ni ode ariya mẹjọ (8) ti wọn ti pe oun si.

Ti ipa oun ko si ka mọ, ninu fọnran ti Biọla ṣe lo ti n kọminu l’ori inawo ti oun yoo nilo ati ṣe fun awọn owanbẹ naa. O pe, bi oun ba ra aṣọ, bata ati baagi to ba aṣọ mu, nkọ? Ọtọ ni owo iṣojuloge (make-up), owo epo si ọkọ oun fun irinajo, bẹẹ oun yoo tun na’wo l’oju agbo ti awọn to n ṣẹ owo yoo si tun yọ ti wọn ni’bẹ. Pabambari ni pe, oun yoo nilo lati fi iṣẹ si’lẹ l’ọjọ naa lati yọ’ju si owanbẹ.

Biọla ni, ni oun to wa niwaju oun yii, ko din ni miliọnu meji naira, eyi ti oun ko si ni. O pe fọnran ti oun ṣe naa ko ma jẹ ti awọn to lọ oun l’ode t’ori o ṣeeṣe ki oun ma le ra aṣọ-ẹbi, ti oun si n gbọ pe aṣọ ni iwọle. Oṣerebinrin ni oun ko kọ bi wọn o ba gbe aṣọ fun oun l’ọfẹ, ṣugbọn ẹni ti ko ba le gba ki oun wọ aṣọ ti oun ni wa ko ma reti oun ni owanbẹ rẹ.

Ọrọ yii ti wa da mẹwaa si’lẹ l’ori ayelujara, ọtọtọ ni iwoye kaluku l’ori rẹ. Awọn kan ni iwọn eku ni iwọn itẹ, bẹẹ awọn miran ni gbajumọ lawujọ kii da’ṣa kosi. Ẹ gbọ, n jẹ lootọ ni owo aṣọ-ẹbi ti fẹ di gb’ẹmi gb’ẹmi?

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search