MI O RI NKAN JẸ, AWỌN ENIYAN L’OUN BUN MI NI TỌRỌ KỌBỌ – OJOGẸ ONITIATA

Ọjinmi elere agbelewo Yoruba, Ṣẹsan Adio ti ọpọ mọ si Ojogẹ lo ti ke gbajare s’aye l’ori bi nnkan o ti danmọran fun-un ati bi ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN ṣe ta oun nu bi akisa ẹlẹgbin.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to gb’omi l’oju ẹni ti oṣere naa ti okiki rẹ kan ni ni nnkan ọdun 1970s ṣe laipẹ yii l’ori Agbalẹtu TV lo ti ṣalaye bo ṣe jẹ pe esun tere tere bi ẹgbẹrun marun-un naira (₦5,000) ẹgbẹrun mẹwaa naira (₦10,000) ti awọn ti oun mọ tipẹ ba fi ta oun l’ọrẹ l’oun fi n ṣe aye. O sọ ọrọ yii pẹlu ọgbẹ ọkan pe gẹgẹ bi ẹni to ti fi igba kan jẹ gbajumọ olokiki.

Ko ṣai mu ẹnu ba bi ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN ko ṣe ya si ọrọ oun, paapajulọ lasiko ti ọmọ oun ṣe alaisi laipẹ yii. Oṣere naa ṣalaye pe asiko diẹ ṣaaju ki gbajugbaja akọni oṣere’binrin nni Peju Ogunmọla o to padanu ọmọ rẹ ni ọmọ t’oun ti kọkọ ja’de l’aye. 

A mọ ṣa to ṣe oun ni kayefi pe iṣẹlẹ ti Peju Ogunmọla nikan ni ẹgbẹ TAMPAN ti wọn ko si nani oun tori pe oun ko ri jajẹ gẹgẹ bi Ojogẹ ti wi.

Ojogẹ ko tun ṣai mu ẹnu ba bi Adebayọ Salami ti ọpọ mọ si Ọga Bello ṣe gbe Sunday Ọmọbọlanle Aluwẹ bori oun ti ko si ran okiki oun l’ọwọ. Oniruuru awọn iṣẹlẹ lagboole tiata ni Ojogẹ mẹnuba, ka ka diẹ, ka da kẹ.

Gbogbo komi, iwoye awọn eniyan l’ori awọn ọrọ ọjinmi elere agbelewo yii ṣe ọtọtọ, bi awọn kan ti n kaanu rẹ ni awọn kan n pe, bi eniyan ba ti tẹ ẹni rẹ ni ṣe sun le.

Baba Ojoge pely Kunle Afod

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search