Afi bi igba ti yinyin ba jabọ le ori ọkan ẹni ni akoko naa ri nigba ti Adejare Kosokọ ti ọpọ mọ si Deja abi Dudukẹ tii ṣe ọmọ bibi inu gbajumọ l’ọkọ-l’aya olorin, iyẹn Adekunle Kosokọ ti awọn eniyan mọ si Adekunle Gold ati aya rẹ Simisola (Ogunlẹyẹ) Kosokọ ti awọn eniyan mọ si Simi gba ọpa gbohun-gbohun (microphone) l’ori itage kan ni ilu London lati gbe “Ẹja Nla” iyẹn baba rẹ, Adekunle Gold wọ’le s’oju agbo niwaju ọgọrọ awọn ero iworan ti inu wọn n dun sikin, ti wọn si n yọ ṣẹṣẹ.
Ninu fọnran kan to ti n ja ranyin l’asiko yii kiri ayelujara ni Dejare ti ki baba rẹ kaabo lati gbe wọ’le si oju agbo. Ọrọ ọmọ naa lọ bayii: “T’ọkunrin t’obinrin, oju gbogbo yin pata lo gun rege l’oni. Ẹ ṣeun tẹ wa wo iran ere baba mi. Mo ki gbogbo yin kaabọ lati wa wo baba mi, Adekunle Gold,” Bi ọmọde’binrin ọlọpọlọ pipe arẹwa yii ṣe n s’ọrọ kọọkan ni ariwo iwuri n ta gee lati ọdọ awọn ero witi to kun inu gbọngan lati wa gba’fẹ, daraya.
Lẹyin eyi ni Adekunle Gold ti ṣe baba ọmọ yii naa fun ra rẹ wọ’le wa ninu aṣọ adabole nla dudu awọn oyinbo (Coat) ti ariwo si ta gẹẹ lati ri gbajumọ olorin yii. Ilu London mi titi ka ma pa’rọ. Ọgọrọ awọn eniyan l’ori ayelujara ni eyi iṣẹlẹ yii wu l’ori gidigidi, to si tun yọ ọkan ọpọ awọn miran ti wọn fi ti ẹbi Kosokọ tọrọ.