ỌLAMIDE BADDO BU EPE JO AWỌN ỌTA RẸ L’OJU AGBO

ỌLAMIDE BADDO BU EPE JO AWỌN ỌTA RẸ L'OJU AGBO, LO BA TUN FI IFẸ HAN SI ERO IWORAN KAN

Otutu ilu London ni awọn ọmọ olorin wa kọọkan lati orilẹ-ede Naijiria n lọ b’awọn fi awọn orin to gbona fẹlli-fẹli gbọn danu kuro l’ara. Ọkan pataki ninu wọn ni Ọlamide Adedeji ti ọpọ mọ si Ọlamide Baddo.

Gbongan OVO Arena ni Wembley ni’lu London ti ogbontarigi olorin naa iyẹn Ọlamide ti lọ patẹ orin laipẹ yii lo kun akunfaya. Lati bi ọdun mẹwaa sẹyin ni eekan olorin naa ti da patẹ orin ti yoo le iwaju rẹ (Concert Headline) ni ilu London. Ero pọ witi lati wa f’orin Ọga Agba ile-iṣẹ agborinjade YBNL naa to ti n ba bọ fun ọpọ ọdun sẹyin da’raya.

Ni’gba ti Ọlamide ati awọn ololufẹ rẹ ba ariya naa de ibi kan to l’apẹrẹ ni Baddo pariwo “Wọn dẹ ni pe baba iya wọn o ni fansi (fan/alatẹle) mọ. Wọn ni ṣ’orire!”

Botilẹjẹpe awọn ọrọ naa wuwo pupo, asiko ati ọna ti Baddo gba sọ jẹ ko kọja bi ọrọ apara.
Ni’bi ariya kanaa yii, lati oju agbo l’ori itage ni Baddo ti kẹfin ero iworan kan to da duro to si ke si awọn eleto aabo lati ya si eni naa “eleto aabo, ẹ jọwọ ẹ yẹ ibẹ yẹn wo, a nilo iranlọwọ papapa… Ṣo ti ya, ṣe gbogbo ẹ ti dara, ṣo ti ya ka bẹrẹ?”

Oju aanu ati ọmọniyan ti Baddo fi han yii ti n jẹ ki awọn eniyan o ma s’ọrọ nipa irawọ olorin miran iyẹn Ẹbunoluwa Damini Ogulu ti ọpọ mọ si Burna Boy to le ọdọmọbinrin kan ati ọrẹkunrin rẹ kuro l’oju agbo rẹ nitori ti wọn da duro lai jo.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search