TINUBU DA NNAMDI KANU SILẸ ABI KO PADANU IBO TO N BỌ – CUBANA CHIEF PRIEST

Gbajumọ alafẹ ọwọ alẹ (Night Life Celebrity) Pascal Okechukwu ti ọpọ mọ si Cubana Priest ti ya aarẹ Bọla Tinubu ni gbolohun l’ori ọrọ Nnamdi Kanu ti ṣe olori fun ikọ IPOB (ti ijọba ti fi ofin de) latari bi ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni ilu Abuja laipẹ yii ṣe da Kanu l’ẹjọ ẹbi ẹsun igbesunmọmi ati sisọ awọn ọrọ to ti da ilu ru da ogun si’lẹ pẹlu ijiya ẹwọn gbere l’ọgba itunirọ. Ọpọ awọn eniyan naa lo ti ni fi ẹnu kun idajọ naa pẹlu ero wọn, ṣugbọn ti Cubana Chief Priest yii da yatọ.

Tẹle idajọ ile-ẹjọ giga lati ẹnu onidaajọ James Ọmọtọṣọ lo mu ki Cubana Chief Priest o da Aarẹ Tinubu l’amọran. O pe bi Tinubu ba fẹran ara rẹ ko paṣẹ ki wọn o tu okun ẹjọ kuro l’ọrun Kanu ni paapaapaa nitori oun gan-an ni olori kaafata (Supreme Leader) fun gbogbo ẹkun ila oorun.

Gbajumọ alafẹ yii ni bi oun ba fi eyin ge ẹran fun Aarẹ o le kọ lati jẹ, ṣugbọn bi oun ba fi sọ ododo ọrọ fun, ki Aarẹ o ma kọ t’ori ewu to wa nibẹ paapaa julọ l’ori atunyansi’po Aarẹ Tinubu l’ọdun 2027 fun saa keji, Chief Priest ni bi Tinubu ba kọ eti ọgbọin, to ba ri ibo ẹgbẹrun mẹwaa (10k votes) ni ẹkun ila-oorun guusu (South East) ko pa aja fun oun jẹ.

Lara ọrọ Cuban Priest re “Aarẹ Tinubu bi MNK (Mazi Nnamdi Kanu) ba ṣi n bẹ ni ẹwọn, o lee lailai ri ibo to to ẹgbẹrun mẹwaa (10k votes) ni ẹkun ila-oorun guusu (South East) bo ba di l’ọdun 2027… N ko gbọdọ ṣ’eke pẹlu rẹ, (mo fẹ ki o mọ pe) Nnamdi Kanu ni olori kaafata fun gbogbo wa ni ẹkun naa.”

Cubana o tun ṣai mu ẹnu ba bi oun ṣe mọ pe awọn alakoso ti Tinubu yan lati ẹkun naa ṣe jẹ ojo ti ko lee sọ ododo ọrọ fun Tinubu bẹẹ lo tun ni ọpọ awọn gomina ati oloṣelu l’ẹkun naa ni eeyan yẹyẹ yatọ si Gomina ipinlẹ Abia, Alex Otti ti ṣe Gomina ipinlẹ MNK fun ra rẹ.

Ko tan si’bẹ, Cubana Priest tun ni “Aṣiwaju to gba mi laaye ni ile ijọba, to tun jẹ aarẹ akọkọ ti n o bọ ọwọ rẹ. N ko le gbagbe anfani beletanse ki n pe ki ijọba naa bajẹ ṣugbọn bi wọn ba ti ṣe ọrọ Kanu ni yoo sọ boya itẹsiwaju abi wọn yo ko angara wọn kuro ni ìjọba.”

Nibi ti ọpọ ti n jẹ ọrọ idajọ ẹwọn gbere fun Kanu l’ọwọ ni Chief Priest naa tun ko igi ati epo si inu aaro naa ti ina ọrọ naa si ti n jo bulabula. Amọ ṣa bi awọn kan ti n yin Cubana Priest pe ọmọ akin to s’ọrọ akin ni, awọn miran n pe n ṣe ni ọkunrin naa n tan ara rẹ jẹ t’ori majesin lo jẹ ni idi oṣelu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search