rawọ oṣere Nollywood kan, Dayọ Amusa to bi’mọ l’ẹyin ọpọ ọdun to ti n reti ni ọmọ rẹ ti pe ọdun kan bayii. Ayẹyẹ ọjọ-ibi ọmọ naa lo tun wa da họwu-họwu miran si’lẹ. Gẹgẹ bii iṣẹ awọn oṣere lati maa ba ara wọn k’ẹyẹ lo mu ki awọn oṣere bi Iyabọ Ojo, Mercy Aigbe, Ọmọwumi Ajiboye, Zainab Bakare, Aisha Lawal, Fọlọrunṣọ Adeọla ati bẹẹ bẹẹ lọ o yọ’ju si’bi ayẹyẹ ọjọ-ibi naa.
Lati oju agbo ti elere ti n da orin ni awuyewuye ti bẹrẹ latari irufẹ orin ko jọ eebu ko jọ ọtẹ ti awọn kan gbagbọ pe o ni ẹni ti o n ba wi.
Ko pẹ ko jinna ni gbajumọ oṣere miran iyẹn Lizzy Anjorin gbe fọnran ja’de to da bi esi ọrọ si ohun to sẹlẹ ni ibi ayẹyẹ ọjọ-ibi ọmọ ọdun kan oun. L’ara awọn ọrọ buruku kanjan-kanjan ti Lizzy sọ re “Awọn were alakisa wo lo n ṣe pati (party), awọn dalemoṣu arugbo wo lo n ṣe pati, awọn oloṣi wo lo n ṣe pati, awọn tan lọ ra ọmọ wo lo n ṣe pati?”
Gbogbo awuyewuye yii lo mu ki iya ọmọ funra rẹ iyẹn Dayọ Amusa o tu aṣiri itakurọsọ (chat) laarin oun ati Lizzy l’ori Instagram ati oun idi ti oun ko fi pada pe wa si ibi ikomọ-ja’de ati ọjọ-ibi ọmọ naa.
Titi di asiko yii ni ọrọ naa ṣi n gbona fẹlli-fẹli ni bi awọn kan ṣe n pe ki Lizzy ko rọra t’ori ọpọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lo ti fẹ ba ni gbolohun asọ tan, ti awọn miran si n kilọ fun Dayọ Amusa lati fi ori ara rẹ pamọ ko ma fa ara rẹ le aye l’ọwọ paapaa julọ l’ori ayelujara.