BRYMO OLORIN FI ARA RẸ JẸ AARẸ ỌNA KAKANFO, LO BA YỌ GANI ADAMS L’OYE

Irawọ olorin ọmọ ilẹ wa kan to kundun lati ma kọrin ni ede Yoruba, Pidgin ati Gẹẹsi ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Ọlawale Ọlọfọọrọ ṣugbọn ti ọpọ mọ si Brymo to kọ orin “Ara N Bẹ” lo ti jade wa pe ara rẹ ni Aarẹ Ọna Kakanfo ikẹrindilogun ilẹ Yoruba.
Ninu fọnran kekere kan to ṣe to si gbe ja’de l’ori ikanni Instagram rẹ lo sọ ọrọ naa pe oun ti yọ Iba Gani Adams kuro ni ipo Aarẹ Ọna ti oun si ti gba akoso ipo naa.

Ẹ ka diẹ ree l’ara ohun ti Brymo sọ ninu fọnran naa “Lati oni yii, mo ti pe ara mi ni Aarẹ Ọna Kakanfo ikẹrindilogun ilẹ Yoruba, mo ti yọ Gani Adams. Yoruba ko ni ọrọ ta n pe “militant.”

A o le gba l’aaye, gbogbo wa dẹ ranti oun ti Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ to fi oju OPC ri, gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti wọn pa ni igba yẹn, a o le pe ọga wọn ni Aarẹ Ọna Kakanfo, ko le tọ’ju awa Yoruba… O dẹ ma dun mọ mi ti Alaafin ba gba bẹ. Bẹẹni, iditẹ gba ijọba ree.” Ọpọ ni ko le pa ẹrin mọ’ra nipa ohun ti Brymo sọ yii ti awọn miran si mu efo pe boya olorin naa ti gbe nnkan to l’agbara lu’ra.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search