IYA FATHIA BALOGUN KU L’ASIKO ỌJỌ-IBI RẸ

Ogbontarigi irawọ oṣere nni, Fathia Balogun ni iya rẹ, Mama Talayo Abẹni Tẹniọla ku l’asiko ayẹyẹ ọjọ-ibi Fathia.
Ayẹyẹ nla alagbara ni ọjọ-ibi ti ọdun marundinlọgọta (55) ti Fathia ṣe, ọgọrọ awọn irawọ oṣere ati ẹni igba-oju-mọ lo kun ibẹ koda to fi mọ awọn kọọkan ti kii ṣaba yọ’ju si’bi ode ariya bii Funkẹ Akindele ati Shaffy Bello. Oniruuru abala ni ayẹyẹ ọjọ-ibi naa pin si, ti Ọganla Fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma si kọ’rin nibi agbo nla to gbẹyin.

Bi ayẹyẹ ọjọ-ibi yii ṣe wa dun to l’arinrin to, ti ọpọ awọn eniyan si wa ba Fathia kẹyẹ. Ko wa jẹ kayefi bi pe iṣẹlẹ nla miran ti ṣubu tẹ ọlọjọ-ibi lai mọ. Mama to bi ọlọjọ ibi gan-an lo ṣ’alaisi lati ọjọ inawo ku ọla ṣugbọn ti awọn ọmọ iya Fathia to ku fi ṣe oku oru nitori ayọ ọjọ-ibi rẹ to n lọ l’ọwọ.
Si iyalẹnu ọpọ awọn to wa si’bi ayẹyẹ naa ati ọgọrọ awọn to n f’oju ba lọ l’ori ayelujara, Fathia gbe ja’de ni ọjọ keji inawo l’ori ikanni ayelujara pe mama oun ti ja’de l’aye lati ayẹyẹ ku ọla ṣugbọn ti awọn mọlẹbi kọ lati fi to oun l’eti nitori ọjọ-ibi.
Adura ati idaro ti wa n lọ l’ọtun l’osi fun Fathia ati mọlẹbi rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search