Charlie Boy tiso agba ninu Wizkid ati Fela ni’bi ija Wizkid ati Seun Kuti se n’tesiwaju

Bi ọtẹ to gbona janjan l’aarin Ṣeun Kuti ati Wizkid ṣe n tẹ siwaju ni ọrọ naa n ka ọpọ l’ara, ti kaluku si n to s’ẹyin igun to f’ara mọ. Bi ara ilu ti n da si ni ko yọ awọn gbajumọ ati amuludun naa si’lẹ.

Ninu awọn gbajumọ amuludun to ti wa mẹnu l’ọrọ l’ori iṣẹlẹ yii ni Charles Oputa ti ọpọ mọ si Charlie Boy. N ṣe ni Charlie Boy bẹ ọrọ naa l’oju patapata, to si fi ero rẹ han lai fi ololo fọ’hun l’ori taa lo tobi ju ninu Wizkid abi Fẹla Anikulapo Kuti gẹgẹ bi elere.

Ni ero Charlie Boy, o pe “Wiz ati Fẹla. Ta lo tobi ju? Wizkid n kọ’rin fun obitibiti ero; papa iṣere n kun; ina n tan yin-yin-yin; owo n s’ọrọ; ami-ẹyẹ n pelemọ; gbogbo aye n p’okiki. Starboy!

“Fẹla ni ti ẹ ko nilo akiyesi ọpọ ero; ina to n jo geeree ni; Kalakuta ni itage ti ẹ; ododo ni ọpa gbohun-gbohun (microphone) ti ẹ.”
Ni kukuru ede, Charlie Boy ni Wizkid jẹ itọkasi idunnu; ijo ati ariya amunigbagbe ironu gẹgẹ bii elere ti Fẹla, ẹwẹ, si jẹ itọkasi arojinlẹ; ọgbọn inu ati akinkanju.

Ko tan si’bẹ, Charlie Boy juwe awọn mejeeji gẹgẹ bii ojinmi irawọ olorin ṣugbọn ti abuda, akọsẹjaye ati asiko wọn yatọ, ti ko si yẹ lati ma fi wọn we ara wọn lati mọ eyi to ga ju. Charlie Boy pe omi ati ina dijọ jẹ alagbara ṣugbọn agbara ọtọtọ lo wa ni ikawọ wọn.

To ba jẹ owo ati faari – Wizkid. Bo ba wa jẹ ijangbara ati ominira – Fẹla. Kaluku lo lẹ faramọ eyikeyi ninu wọn bi o ba ti ṣe ba wọn pade.

Ẹwẹ, Ṣeun Kuti to kọkọ gun ẹṣin Wizkid ni kẹṣẹ ko to tapa pe oun naa tobi ju Fẹla Anikulapo Kuti lọ tii ṣe baba Ṣeun Kuti. Ọrọ yii ko ti tan rara, ọpọ awuyewuye ati ariwoye l’aarin igboro ati l’ori ayelujara lo ti tẹle ina ọtẹ to n jo geeree yii.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search