Dele Momodu to jẹ gbajumọ oniroyin, ilumọọka ati oloṣelu lo dabi ẹni pe o jabọ kuro l’ọwọ apọnle Davido iyẹn gbajumọ olorin ilẹ wa, to tun jẹ ololufẹ atijọ ati baba ọmọ fun Sophia Momodu t’oun jẹ ibatan si Dele Momodu.
Ko ru’ju pe nnkan o lọ deede lati igba pipẹ sẹyin l’aarin Davido ati Sophia ti ọrọ wọn a si ṣaba ma di ariwo l’ori ayelujara botilẹjẹ pe ọmọ n bẹ l’aarin wọn, iyẹn Imade Adeleke. Koda wọn ṣẹṣẹ tun ti ile-ẹjọ de ni l’ori akata ta ni ọmọ yoo wa, ti ọrọ naa si tun mu ki nnkan o pakasọ si l’aarin wọn dipo ko yanju.
Dele Momodu laipẹ yii lo ṣe atẹjade kan l’oju opo ti ẹ l’ori ikanni Instagram pe “Ni Liberia ni’bi, bi oriṣa orin wọn mu Davido. Mo ti n wa si orilẹ-ede yii, ogun ọdun ti kọja ṣugbọn eyi yatọ nitori to jẹ fun ti arafẹraku ọmọ kan ṣoṣo ti igbakeji Aarẹ orilẹ-ede Liberia to ja’de l’aye. Lati igba ti mo ti wa de, awọn ololufẹ Davido ko jẹ ki n sinmi, ti ọkan ninu wọn @Lorine.Doe si tun beere Sophia pe yoo dun mọ oun bi oun ati Davido ba le pada.”
Dele Momodu to tun jẹ ọrẹ si mọlẹbi Adeleke pari atẹjade rẹ bayii pe “Ati n ṣiṣẹ l’ori rẹ l’abẹlẹ, ko si wahala kankan. Ẹ tunbọ ma fi adura ran wa l’ọwọ.” Ọrọ yii lo jọ n pe Davido ganni to fa bi o ti d’ẹyin l’ẹyin (unfollow) Dele Momodu l’ori ikanni Instagram, ti eyi si ti mu ki awọn aye o ma kọ ha pe ki la gba ki la ju l’ori igbesẹ ti Davido gbe ọun ṣugbọn ti awọn kan ko ri oun to buru ni’bẹ pe n ṣe ni Davido n dabobo ara rẹ.