Gbajugbaja alawada ọmọ ilẹ yii kan, Oluwaṣeyi Lawrence ti ọpọ mọ si Ṣeyi Law lo ti ja’de wa tọrọ aforijin fun awọn ọrọ kan to bọ l’ẹnu rẹ l’asiko itakurọsọ (debate) kan to ṣe laipẹ yii pẹlu onwoye ati ayanana ọrọ ilu (public affairs analyst) kan to wa lati ipinlẹ Edo, to si tun gbajumọ l’ori ayelujara, iyẹn Zekeri Idris Jnr.
Awọn mejeeji lo ti kọ gbe’na wo’ju ara wọn l’ori eto ‘Honest Bunch’ ni’bi ti itakurọsọ naa ti wa’ye. Ọrọ oṣelu orilẹ-ede Naijiria paapaa julọ ni’pa ijọba Aarẹ Bọla Tinubu ati igbiyanju Peter Obi lati de’po aarẹ lo fa ariyanjiyan fọ’po-mọ’yọ naa ninu eyi ti Ṣeyi Law ti fi iwanwara s’ọrọ ni’pa ọrọ eto aabo, l’eyi to bọ si apo ibinu awọn kọọkan l’aarin ilu, ti awọn si bẹrẹ si ni sọ’ko ọrọ pada lati nu Ṣeyi l’ọrọ.
L’ọwọ yii, Seyi Law lo ti wa bọ si’ta ninu fọnran kan to gbe ja’de l’ori ikanni Instagram rẹ to fi n tọrọ aforijin l’ori ọrọ eyi to n ba fi igbona’ra sọ ti ko si dadun mọ awọn eniyan, ki wọn o f’ọwọ wọ’nu paapaa julọ l’abala ọrọ eto aabo.
Ni’pari, Seyi jẹ ko di mimọ pe botilẹjẹpe adiyẹ ijọba Aarẹ Tinubu n l’aagun lat’ari itiraka ati ilaka ṣugbọn ti oun tun rọ wọn lati tunbọ ji giri mọ iṣẹ amojuto ọrọ eto aabo.
Bi awọn kan ti wa n ki Seyi Law ku ọmọ akin ṣe pe o ja’de wa tọrọ aforijin, bẹẹ l’awọn miiran kọ lati jẹ eburẹ ti wọn si tun nu l’ọrọ tẹsiwaju.