Oṣelu Koro, Daniel Bwala Ko Gbogbo Ọrọ Rẹ Jẹ Nipa Tinubu

Ọkan pataki ninu awọn agbẹnusọ fun Aarẹ Orilẹ-ede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Tinubu ti orukọ rẹ n jẹ Daniel Bwala l’aye n s’ọrọ rẹ bayii lẹyin ti ọkunrin naa ko’pa l’ori eto kan ti wọn pe ni “Head to Head” pẹlu gbajugbaja atakurọsọ (debater) kan Mehdi Hasan l’ori ile-iṣẹ amohunmaworan agbaye Al Jazeera.

Ipa ti Bwala lọ ko l’ori eto naa lati s’ọrọ gbe ijọba Tinubu l’ẹsẹ l’ori awọn ọrọ bi eto aabo; igbogun ti iwa jegudujera; igbaye-gbadun ara ilu ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣugbọn n ṣe ni jẹbẹtẹ gbe ọmọ le Bwala l’ọwọ l’atari ọgọrọ awọn ẹsun kanjan ati orukọ buruku ti Bwala fun’ra rẹ ti fi kan ati pe Bọla Tinubu nigba to wa l’ẹgbẹ alatako, ko to darapọ mọ ìjọba Tinubu.

Ẹwẹ, ẹ ranti pe Bwala to jẹ agbẹnusọ iṣejọba Tinubu yii naa lo tun jẹ agbẹnusọ fun ipolongo ibo fun igbakeji Aarẹ tẹlẹ ri, Atiku Abubakar l’asiko ipolongo ibo ọdun 2023 to kọja lọ, ko to di pe Bwala tọrọ aforijin lọwọ Tinubu to si darapọ ẹgbẹ oṣelu APC pada, botilẹjẹ pe o ti kọkọ fi igba kan naa ni iṣaaju wa ni APC, ko to ṣẹ’ri lọ PDP, ko to tun ṣẹ pada si’nu ijọba APC Tinubu lẹyin eto idibo gbogbogboo ọdun 2023.

Awọn aiduro dede nidi oṣelu ati ọrọ ti ko j’ọkan lo gbe jẹbẹtẹ le Bwala l’ọwọ, n ṣe ni atọkun eto naa iyẹn Mehdi lọ n gbe awọn ọrọ kobakungbe ti Bwala ti sọ tẹlẹ si Tinubu ati ẹgbẹ APC ja’de. L’ara wọn ni ẹsun pe Tinubu fi ọkọ agboworin (Bullion Van) ra ibo ri, omiran tun ni ẹsun pe ara Tinubu ko mọ l’ori ẹsun lilọwọ ninu okoowo egboogi oloro nigba kan ri l’orilẹ-ede Amẹrika l’aarin awọn ẹru ọran ti Bwala ti di le Tinubu l’ori l’asiko to jẹ alatako.

Ọkan pataki ninu awọn agbẹnusọ fun Aarẹ Orilẹ-ede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Tinubu …

Ile ise olopa ti orile-ede Nigeria ti yo oga olopa Benjamin Hundeyin …

Gbajugbaja alawada ọmọ ilẹ yii kan, Oluwaṣeyi Lawrence ti ọpọ mọ si …

Ọga agba ile-iṣẹ iwe iroyin alariya, Ovation Magazine to tun ti fi …

Ọgọrọ awọn eniyan l’ori ayelujara lẹyin eto naa ti wa n gbe oniruuru awọn ọrọ lile ti Bwala ti sọ sẹyin nipa Tinubu ati ẹgbẹ APC l’ori atẹ aṣikaye ati l’ori amohunmaworan.

L’aarin bi gbogbo ọrọ yii ṣe wa n lọ, Bwala fun’ra rẹ ti ja’de s’ọrọ lẹyin eto naa pe ohun ko mọ pe wọn yoo mẹnuba awọn ọrọ oun lati ẹyin to tako Bọla Tinubu, iṣejọba ati ẹgbẹ oṣelu rẹ ṣugbọn ti oun yoo ma gbaradi de anfani miiran lati wa fọ ara rẹ mọ ju bayii lọ. Bi awọn kan ti n da hẹ Bwala pe ọkunrin naa ba ọmọ jẹ patapata, ti ọrọ rẹ ko si j’ọkan nitori adun ipo to wa, bẹẹ ni awọn miran fi aduroti han si pe kosi ohun to buru nitori eniyan le pa ọna oko da anbelentase ọrọ ẹnu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search