Wón ti yo ògá olopa Benjamin Hundeyin.

Ile ise olopa ti orile-ede Nigeria ti yo oga olopa Benjamin Hundeyin to je alukoro fun ile-ise olopa lorile-ede Nigeria kuro ni ipo naa ni ojo karùn-ún osu keta odun 2026.
Eleyii wa s’aye leyin osu mefa ti oga olopa agba ti orile-ede Nigeria tele, iyen oga olopa Kayode Egbetoku yan an si ipo naa.
Akojopo iwadi ti ile ise iroyin itafaaji se fi idi re mule pe oga agba fun ile ise awon olopa orile-ede Nigeria tuntun ti Aare Tinubu sese yan sipo, iyen oga olopa agba Olatunji Disu lo fi onte lu yíyo ti won yo Hundeyin ni ojóbò ose yii (5/3/26).

Ohun ti a ko ti i le fi idi re mule bayii ni ohun to fa a ti oga olopa agba Olatunji Disu fi yo oga olopa Benjamin Hundeyin kuro ni ipo alukoro fun ile-ise olopa lorile-ede Nigeria.
Akoroyin wa salaye pe ohun to sele yii waye lasiko ti ile ise awon olopa orile-ede Nigeria n se atunto laarin awon logaloga ni olu ile ise awon olopa orile-ede Nigeria lowolowo bayii.
Eni to salaye oro yii fun akoroyin wa l’Abuja to si so pe oun o fe ki a dárúko oun pe oun lo salaye oro yii fun akoroyin wa fi idi re mule pe won ti yo oga olopa agba, Benjamin Hundeyin kuro ni ipo alukoro fun awon olopa orile-ede yii lowuro ojóbò, Tósìdéè, 5/3/26.

Ose to koja ni Aare orile-ede Nigeria, Bola Ahmed Tinubu yan oga olopa Olatunji Disu si ipo oga olopa agba ti orile-ede Nigeria, ti oun si jé oga olopa agba eléèketàlélógún (23rd) leyin igba ti won ti yo oga olopa agba tele, Egbetokun to ti di ipo naa mu lati odun 2023.
Egbetokun naa lo si yan oga olopa Benjamin Hundeyin sipo alukoro fun awon olopa orile-ede Nigeria ni osu kesàn-án, odun 2025 (September 2025).

Hundeyin ti won yo yii je eni to ti fi igba kan je agbenuso fun olu ile-ise olopa ti ipinle Eko (Lagos police command) nigba to gba ise lowo oga olopa Muyiwa Adejobi ti won gbe lo si olu ile ise olopa ti ipinle Delta.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search