Onigbinde, Koshi Super Eagles Tẹlẹ ti Ja’de L’aye

Ogbontarigi akọnimọọgba (coach) tẹlẹ fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu agba-ọjẹ ilẹ wa iyẹn Super Eagles to tun jẹ Agba-Oye Ọtun Balogun ni ilu Modakẹkẹ ni ipinlẹ Ọṣun – Agba-Oye, Festus Adegboye Onigbinde ti ja’de l’aye ni ọjọ kẹsan oṣu kẹta ọdun 2026 yii l’ẹni ọdun mejidinlaadọrun (88) gẹgẹ bi awọn mọlẹbi eekan lẹka ere idaraya naa ṣe kede, ti wọn si n tọka si awọn oripa manigbagbe ti akọni oloogbe naa fi le’lẹ l’agbo ere idaraya, idari, ati ṣiṣe iṣẹ sin ilu.

‘Koṣi Onigbinde’ bi ọpọ ti mọ si nigba aye rẹ lo fi itan manigbagbe balẹ gẹgẹ bi ọmọ ilẹ yii akọkọ lati jẹ akọnimọọgba fun ikọ agba-ọjẹ ilẹ wa lati igba to n jẹ ‘Green Eagles’ ko to wa di ‘Super Eagles’. Ọlọpọlọ pipe ẹda, onijanu, ati olufọkansin tootọ ni Onigbinde jẹ nigba aye rẹ ti ipa rẹ ko si ṣe ko danu ninu idagbasoke ere bọọlu alafẹsẹgba l’orilẹ-ede Naijiria.

L’ara aṣeyọri manigbagbe akọni Akọnimọọgba yii ni jijẹ akọnimọọgba l’abẹle akọkọ lati ko ikọ Super Eagles de ipele asekagba ninu idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ ni ọdun 1984 botilẹjẹ pe wọn ayo igbeyin naa pada ja mọ orilẹ-ede Cameroon l’ọwọ. Bẹẹ ni ọlọpọlọ pipe akọnimọọgba yii tun gbe orilẹ-ede Naijiria de inu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA l’ọdun 2002 ni orilẹ-ede Kore ati Japan. Ko tan si’bẹ , Onigbinde tun fi igba kan jẹ akọnimọọgba fun ikọ Shooting Stars SC ti ilu Ibadan to si gbe wọn de ipele asekagba idije “African Club Champions Cup” botilẹjẹ pe ikọ Zamalek lati orilẹ-ede Egypt lo pada gbe igba oroke.

Yatọ fun pe Onigbinde jẹ akọnimọọgba to dangajiya, o tun jẹ ọkọ rere, baba, baba-baba, baba-nla, ọrẹ ati oloye pataki nilu Modakẹkẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search