Agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan, Daniel Daga ni ile-ẹjọ kan l’orilẹ-ede Norway ti da’jọ ewọn fun bayii l’ori jij’ẹbi ẹsun ibalopọ lai gba iyọnda.
Agbabọọlu ẹni ọdun mọkandinlogun (19) ti’nu ikọ Flyin Eagles ilẹ wa to tun gba bọọlu jẹun nilẹ okeere ninu ikọ Molde FK ni orilẹ-ede Norway ni adajọ pe ko lọ ṣewọn oṣu mẹfa, ko si tun san adapada ẹgbẹrun mẹwaa Kroner (10,000 Kroner) owo orilẹ-ede Norway ti wọn fi ṣe ẹjọ. Ẹwẹ, awuyewuye ọrọ ẹjọ Daga yii lo bẹrẹ ni nnkan oṣu kẹrin (April) ọdun 2025 l’asiko ti wọn mu ọrọ rẹ lọ sun ile-iṣẹ ọlọpa ni orilẹ-ede Norway, ti ọrọ naa si pada yọri si ile-ẹjọ pe Daga ni Ibalopọ ti ko ni iyọnda ninu, ti eyii si kọlu abala kẹtadinlọọdunrun (Section 297) iwe ofin orilẹ-ede Norway.
Siwaju si, amofin to gb’ẹjọ ro fun Daga nile ẹjọ, Astrid Bolstad ni onibara koro oju si idajọ naa nitori ti ko lero pe ẹjọ naa le b’ẹyin yọ latari pe ibalopọ ti awọn naa ni jẹ ohun to ni ifọwọsi awọn mejeeji ninu.
Agbẹjọro wa sọ di mimọ pe, idajọ naa ko ti le duro nitori ti awọn yoo pe’jọ kotẹmilọrun l’ori idajọ naa botilẹjẹ pe Daga ko ni le kopa ninu ifewọnṣẹ titi ọrọ naa yoo fi yanju. Ẹwẹ, Tarje Nordstrand Jocobsen to jẹ alaga ikọ ẹgbẹ agboolu ti Daga n gba fun ti ṣalaye pe ohun to l’agbara gan-an ni iṣẹlẹ yẹn ti awọn yoo si jẹ ki ofin ṣiṣẹ ọwọ rẹ ṣugbọn ti di igbayegbadun agbabọọlu awọn l’ọwọ