Ẹ tún kù ú déédéé àkókò yí o ẹ̀yin olólùfẹ́ wa gbogbo. Ṣé dáadáa la báayín? Àjíǹde ara ẹnìkọ̀ọkan wa yoo maa jẹ́ o.
Lábala ÒÒYE AYÉ lónìí, ohun tí mo fẹ́ ká gbéyẹ̀wò nííṣe pẹ̀lú èmi àti ẹ̀yin táajọ ń f'òye bá abala yí bọ̀. Àkọ́lé tòní la ó sì pè ní "KÍ NI ÌKỌ̀KỌ̀ ÀWỌN ÒBÍ RẸ"?
Ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) ti gbe idajọ gbe’le ẹ alainigbedeke (indefinite suspension) kalẹ fun ẹni to jẹ ekan l’ara awọn …
Gbogbo wa pátá la má ń ṣàpọ́nlé àwọn òbí wa pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ fúnwọn gẹ́gẹ́ bí awọ̀n ìwé mímọ́ ti là á kalẹ̀ fúnwa. Nítorí pé àwọn ni ọ̀run wa. Ọ̀pọ̀ nínú wa la máa ń sọ pé Ìyá tàbí Bàbá wa ló dára jù nínú gbogbo ìyá àti Bàbá tíḿbẹ láyé, nítorí ìfẹ́ táaní síwọn gẹ́gẹ́bí ọlọ́kọ̀ tó wàwá wá sáyé. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò mọ ìkọ̀kọ̀ wọn bóyá ìwà tí wọ́n ni ló ń lànà fúnwa tàbí fìyà jẹ wá nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé wa.
Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdojúkọ tí ẹlòmíràn ń ní láyé kó jẹ́ pé ìkọ̀kọ̀ òbí ẹ ló ń dá sẹ̀ẹ̀ríà fún un. Àìmọye ìyá tàbí Baba ló jẹ́ abatẹnijẹ́ nínú ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí ló sì jẹ́ olubi ènìyàn, àmọ́ èyí kì í hàn sí ọmọ wọn rárá leyi tí yóó sì mu máa ríwọ̀n gẹ́gẹ́bí ẹni rere. Ṣe àwọn àgbà Yorùbá sì bọ̀, wọ́n ni bí àlọ bá lọ, àbọ̀ ń bọ̀. Kò sí ohun kan táaṣe nílé ayé yi tó gbé.
Nítorí náà ìwọ olùkàwé mi yí, bí o bá wà nínú làásìgbò ayé kan tí nkan ò fẹ́ẹ́ jọraawọn fún ẹ, gbìyànjú kó o ronú ẹ láròjinlẹ̀ wípé ṣé kì í ṣẹ ìkọ̀kọ̀ àwọn òbí rẹ tóòmọ̀ ló ń fìyà jẹ ọ́. Nítorí púpò nínú àwọn ìwà àìdà tí àwọn òbí wa ti hù sẹ́yìn lè maa ṣàkóbá fúnwa lọ́jọ́ òní. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé, nígbà kigbà tí a bá ń ṣ’àdúrà, a ní láti máa sọ wípé kí Olódùmarè ọba àdáni wáyé ó má fi ìkọ̀kọ̀ àwọn òbí wa biwá.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ló ń bẹ nínú ìpọ́njú báyìí tó ṣe pé ẹ̀san iṣẹ́ẹbi tí awon òbí ẹ̀ ti ṣe sẹ́yìn ló ń ké lórí wọn. Àwa ọmọ kì í mọ̀. A sábà máa ń rí àwọn òbí wa bí áńgẹ́lì, láìmọ̀ wípé ìkà, aṣebi ni ẹlòmíràn nínú wọn.
Nítorí náà ọrẹ mi, gbìyànjú o máa ṣe é mọ́ àdúrà wípé k’Élédùmarè ó má fi ìkọ̀kọ̀ àwọn òbí rẹ tí kò sunwọ̀n dá ẹ lẹ́jọ́ o. Nítorí a kì í mọ̀kọ̀kọ̀ wọn.
Lábẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí gbogbo àwa ti a jẹ́ òbí náà o máa hùwà rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Kì í ṣe nítorí ohun méjì, bí kò ṣe nítorí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wa. Gbogbo ohun taaba ṣe loni, làwọn ọmọ wa máa padà kó ẹ̀san rẹ.