Baba Ijẹṣa, Yo Orukọ Awọn Ọmọ L’ẹnu Rẹ abi Ko R’ogun Ẹjọ L’ẹẹkan si – Iyabo Ojo

Gbajugbaja oṣere tiata ati alawada, Lanre Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijẹṣa ni irawọ oṣere’binrin, Iyabọ Ojo ti ki nilọ bayi lati ma mu orukọ awọn ọmọ oun mọ ẹnu nini igbiyanju rẹ lati ro arojare abi wẹ ara rẹ mọ l’ori ọran biba ọmọ kekere ọmọ ọdun mẹrinla kan ta’mi oge ni nnkan ọdun diẹ sẹhin, leyii to sọ Baba Ijẹṣa di ero ọgba itunirọ, l’eyi to ṣe dari de kuro nibẹ.

Baba Ijẹṣa lo ri ẹwọn he l’aarin oṣu keje (July) ọdun 2022 si oṣu kọkanla (Nov) ọdun 2025 lẹyin ti ile-ẹjọ pe o jẹbi wiwu iwa ko tọ pẹlu ọmọ arobo kan.

Ninu igbiyanju Baba Ijẹṣa lati fọ ara rẹ mọ l’ori iṣẹlẹ naa lẹyin to ti ẹwọn de. O ṣalaye pe irọ gbu lasan ni Princess ati awọn ẹmẹwa rẹ pa mọ oun l’ori ẹsun naa nitori ti oun kii ṣe iru eniyan bẹẹ ati pe oun ko hu iru iwa palapala bẹẹ ri. Bẹẹ lo ni iyalẹnu nla lo jẹ fun oun pe Iyabo Ojo to ma n fi awọn ọmọ rẹ ṣọ oun ni kekere naa le pẹlu awọn to n fi irufẹ ẹsun buruku naa kan.

Ninu ọrọ rẹ ni Baba Ijẹṣa ti mẹnuba Iyabọ Ojo, to jẹ ọkan gboogi ninu awọn alatako fun Baba Ijẹṣa lasiko wahala ẹjọ naa.

Iyabo ti wa ṣe ikilọ fun Baba Ijẹṣa lati dẹkun dida orukọ awọn ọmọ rẹ, iyẹn Priscilla ati ẹgbọn rẹ ninu aroye abi awijare kankan to ba fẹ ṣe bibẹkọ oun yoo jẹ ki Baba Ijẹṣa tun r’ogun ẹjọ lẹẹkan si.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search