Wahala nla lo bẹ silẹ lana ode yi ni’lu KuGompo to wa ni agbegbe ẹkun ilaoorun Cape ni orilẹ-ede South Africa ni’gba ti awọn ọmọ ilu kọọkan korajọ labẹ asia ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ActionSA lati fi ẹhonu han tako ohun ti wọn kẹfin pe awọn alejo-olugbe agbegbe naa to je ẹya Igbo lati orilẹ-ede Naijiria ti fi Solomon Ogbonna Eziko jẹ oye “Igwe Ndigbo” iyẹn “Ọba awọn Igbo” ninu ilu abinibi wọn, ti eyi ko si tẹ wọn l’ọrun rara. Ifẹhonuhan awọn eniyan naa lo mu ijamba ati iwa ipa dani, ti wọn si da’na sun awọn dukia olowo iyebiye bi ile, ọkọ, ati ile itaja ti wọn kẹfin pe o jẹ ti awọn olugbe agbegbe naa to jẹ ẹya Igbo. Wahala naa buru to bẹẹ gẹ de bi pe awọn ọlọpa lo pada gbakoso oju ọjọ l’agbegbe naa.
Ẹwẹ, Athol Trollip to jẹ alaga fun ẹgbẹ ActionSA ni ẹkun naa ṣalaye pe awọn lodi si fifi ọba kankan jẹ ni agbegbe naa nitori awọn ni awọn olori ilu to jẹ iṣẹmbaye, ati pe iriri buruku ti awọn ti ni s’ẹyin nipa awọn to ma gba ilẹ kuro l’ọwọ awọn ọmọ oniluu ko le jẹ ki awọn f’aye gba awọn eeyan Igbo lati jọba paapaa julọ, awọn kẹfin pe n ṣe ni wọn ranṣẹ pe awọn eeyan Igbo to ku ni orilẹ-ede Naijiria lati wa mu ilẹ si ilu awọn.
Siwaju si, ile-iṣẹ to n ṣ’oju ijọba orilẹ-ede Naijiria ni orilẹ-ede South Africa ti ṣ’alaye pe Naijiria ko gba l’ero lati jẹ gaba l’ori agbegbe kankan ni South Africa ṣugbọn to kan jẹ pe awọn ọmọ Naija kan jẹ ẹnikan to gbe aṣa l’ori gidi gan. Ile-iṣẹ naa wa parọwa f’awọn ọmọ Naijiria ni agbegbe naa ati kaakiri lati ma gba alaafia l’aaye, ki wọn o si ma tan awọn ọmọ oniluu ni suuru.
Oniruuru iwoye lo ti n ja ranyin-ranyin kaakiri l’ori ọrọ yii, awọn kan n pe iriri ọgbẹ ati iriri inira imunisin ati ijẹgaba awọn oyinbo ijọba Apartheid ni ko tan bọọrọ l’ara awọn ọmọ Southy, ṣugbọn ti awọn kan n pe ọyaju ati ọfinran pọ ninu awọn ọmọ Naija. Bẹẹ awọn miiran gbagbọ pe afibisu oloore ni awọn ọmọ Southy nítori pe orilẹ-ede Naijiria gba wọn ni’tẹ nigba ti oju n pọn wọn latẹyin wa.
Violent protests erupted in KuGompo City (East London) in the Eastern Cape province of South Africa in late March 2026, targeting foreign-owned property following the controversial coronation of a Nigerian Igbo community leader. Protesters torched vehicles and buildings,, particularly in areas near the Eastern Cape, due to the installation of Solomon Ogbonna Eziko as “Igwe Ndigbo” (Igbo King) on March 24, 2026.