Funkẹ Akindele: Mo Buru, Emi Naa Dẹ Mọ

Gbajugbaja ogbontarigi oṣerebinrin ọmọ ilẹ wa nni, Olufunkẹ Akindele ti ọpọ mọ si Jennifer lo ti ja’de ṣalaye ọpọ awọn oun ti aye ko mọ nipa rẹ ati irufẹ ẹda to jẹ.

Jennifer ṣe awọn alaye pataki naa l’ori eto ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu irawọ agbohunsafẹfẹ, Morayọ Afọlabi Brown laipẹ yii. Ninu ifọrọwerọ wọn, Funkẹ ṣ’alaye pe oun jẹ ẹda lile ṣugbọn ti ki ṣe eke rara, koda nigba mi oun a ma fẹ da bi onisọnu.

Siwaju si, gẹgẹ bii idahun si ibeere Morayọ, Funkẹ gba pe oun a ma gbe imọlara l’ori gẹngẹ to jẹ pe bi oun ba fẹran eniyan, de oju ogongo, bi eniyan ba si yẹpẹrẹ ara rẹ, oun ko ni kọ lati fi iru ẹni bẹẹ si aaye rẹ.
Ko ṣai mẹnuba ibaṣepọ to dan mọran to wa laarin oun ati awọn ọmọ iya oun lai fi ti bi oun ṣe jẹ ilumọọka ṣe.

Ẹwẹ, Funkẹ ẹni ti awuyewuye ṣe wa’ye nipa rẹ ati gbajugbaja irawọ oṣerebinrin miiran, Toyin Aimakhu Abraham nibi ayẹyẹ ifilọlẹ sinima tuntun lat’ọwọ Iyabọ Ojo ṣalaye pe o gba oun ni ọpọ iṣẹ takuntakun lati le m’oke nidi iṣẹ ere, ti oun ko si ni ọrẹ lọ titi ṣugbọn to jẹ pe o pe oun bẹẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search