Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra to tun jẹ oludije tẹlẹ ri si ipo Aarẹ, Peter Obi ti pe oun ko ni fi aaye gba iwa ọdaran kankan lẹka epo ni orilẹ-ede Naijiria bi oun ba le di Aarẹ.
O sọrọ yi l’asiko to n kopa ninu ifọrọw’ọrọ kan ni ile-iṣẹ amohunmaworan Trust TV, nibẹ lo ti ṣalaye pe jibiti nla lo wa nidi owo iranwọ epo (oil subsidy) ati pe iwa jẹgudujẹra aiti aiṣododo pọ lẹka ọrọ epo ati onka ni pato iye jaala epo ti Naijiria n lo lojumọ.
Obi ṣakawe orilẹ-ede Naijiria pẹlu orilẹ-ede Pakistan pe onka iye awọn eniyan ni orilẹ-ede mejeeji sunmọ ara wọn ṣugbọn iye epo ti Naijiria n lo loojọ pọ pupọ ju ti Pakistan ti eyi si n tọka si iwa jẹgudujẹra ati aiṣododo.
Ta lo n gbọn epo wa mu? ni ibeere ti Obi n takoto.
Ẹwẹ, Obi, ẹni to ṣe ipo kẹta ninu eto idibo to waye kọja ni ọdun 2023 pẹlu ẹgbẹ oṣelu Labour ṣugbọn to ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADC l’asiko lo ti n sa ipa lati dije pada ninu eto idibo gbogbogboo t’ọdun 2027 to n bọ lọna.