Fri, 20th March, 2026

Mummy G.O: Mo Binu Sọ Ẹṣọ Goolu Mi S’okun Lẹyin Ti Mo Gba Jesu Tan

Mọmi G.O ijọ onirapada iyẹn ṣọọṣi R.C.C.G, Mama Folukẹ Adeboye to tun jẹ aya fun alamojuto agba ijọ naa iyẹn Dadi G.O Adejare Enoch Adeboye lo sọ awọn ọrọ kan to ti n mi ori ayelujara ti-ti.

Mama naa pe l’ẹyin ti awọn di atunbi ninu Oluwa ti awọn si gba Jesu kristi s’aye wọn la wọn ba pa’lẹ awọn ẹṣọ goolu (wura) olowo iyebiye ti awọn ni, ti wọn si ko danu s’odo.

Eyi lo jẹ yọ ninu alaye ti Mọmi G.O ṣe pe awọn naa fẹran kiko ẹṣọ ara bi goolu jọ nigba ti awọn naa wa ninu aye bi ọpọ awọn obinrin yooku. Koda ti awọn tun ti pese lẹ de ọmọ.Amọ ṣa, lẹyin ti Mama naa darapọ mọ ijọ onirapada ti ko f’aaye gba kiko ẹṣọ kọ’ra l’asiko naa mu ki awọn o jọwọ gbogbo oun ti ṣe t’aye, t’awọn si gba’ju mọ ti Oluwa, ti awọn si dupẹ l’oni nitori ti ko si abamọ kankan fawọn l’ori ipinu ati igbesẹ naa titi di oni. Koda, awọn to da wọn l’amọran lati ko fun mama awọn dipo sisọ awọn ọṣọ ara naa s’odo ni awọn jẹ ko ye pe “ohunkohun ti ko ba ti dara fun mi, ko dara yẹ fun Mama ni naa.”Ẹwẹ, oniruuru ni iwoye awọn onwoye l’ori ọrọ yii, bi awọn kan ti n pe ijọ naa l’eni ti fi aaye gba lilo ọṣọ ara ni awọn miiran n pe ọmọ t’aye bi l’aye n pọn.https://itafaaji.com

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search