Itafaaji

King Sunny Ade, Ọba awọn Oṣere Juju

Laipẹ yii ni gbaju-gbaja onkọrin taka-sufee (hippup) kan, Ọgbẹni David Adeleke, ti wọn n pe ni Davido, tabi OBO, iyẹn Ọmọ Baba Olowo, gẹgẹ bi awọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e, ṣe igbeyawo alarinrin pẹlu aya rẹ, Chioma, niluu Eko, ẹsẹ ko si gbe’ro lọjọ naa, ọgọọrọ awọn eeyan nla-nla bii aarẹ tẹlẹri, awọn gomina, ọba alaye nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo, awọn olokoowo nla, atawọn oṣere atijọ ati ti ode-oni ti wọn lorukọ lawujọ, lo wa.

Nibi iru ayẹyẹ to tobi to si larinrin bii eyi, ta ni oṣere to kọrin lọjọ naa, to kan ilu si awọn eeyan pataki pataki wọnyi n’ibadi, ti gbogbo wọn si fi ẹsẹ ra ijo?
Gbajumọ ọba orin Juju kan ti wọn n pe ni King Sunny Ade ni, Oloye Sunday Iṣọla Adeniyi Adegẹye.

Ka yọ t’ẹgan kuro, ẹfọ odu ni King Sunny Ade tabi KSA lagbo awọn oṣere to lookọ nilẹ Yoruba, lorileede Naijiria, nilẹ Africa ati kari agbaye, ki i ṣaimọ fun oloko rara, tori ọjọ rẹ ti pẹ gan-an lagbo ariya, ọjọ aboki rẹ ti pẹ ninu egungun daadaa.
Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1946 ni wọn bi Sunny Ade, ọdun 2024, ni oṣu meji si asiko yii lo maa di ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78) loke eepẹ. Oun lawọn eeyan sọ pe o jẹ oṣere olorin gita ọmọ ilẹ adulawọ, ilẹ Africa, to maa kọkọ di ilumọ-ọn-ka olorin kari aye, to si rọwọ mu nidi iṣẹ naa daadaa.
Ẹ jẹ ka sọrọ nipa bi Sunny Ade ṣe ṣe kekere rẹ. Ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun bayii ni wọn bi ọmọ olokiki yii si, amọ nigba naa ko ti i si ipinlẹ Ọṣun, abẹ ipinlẹ Ondo ni gbogbo wọn wa. Idile ọlọba ni Sunday Adeniyi ti wa, ila idile to n jọba niluu Akurẹ ati ni ilu Ondo ni awọn obi rẹ mejeeji, tori naa, Ọmọọba ni lọtun-un losi.

Ka yọ t’ẹgan kuro, ẹfọ odu ni King Sunny Ade tabi KSA lagbo awọn oṣere to lookọ nilẹ Yoruba, lorileede Naijiria, nilẹ Africa ati kari agbaye

O jọ pe ile ni ọkunrin naa ti ba iṣẹ ere, nitori ọkan ninu awọn atẹduuru ni ṣọọṣi ni baba rẹ. Duuru ni oriṣii nnkan eelo ikọrin kan tawọn oyinbo n pe ni Organ, o jọra pẹlu eyi ti wọn n pe ni Piano lode oni, amọ o ti ṣaaju Piano de, o si tobi pupọ ju Piano lọ. Duuru yii wọpọ ninu awọn ṣọọṣi laye atijọ, tori oun ni wọn maa n lo lati fi kọrin ẹmi, iró ati ohùn rẹ lawọn ọmọ-ijọ maa tẹle ni gbogbo ọjọ Isinmi, iyẹn ọjọ Sannde, tabi ọjọ Aiku, lọsọọsẹ ti eto ijọsin ba maa waye. Oniṣowo ni Mama rẹ, Oloogbe Maria Adegẹye, idile Ọba Adeṣida to jọba ilu Akurẹ fun ọpọ ọdun lo si ti wa.
King Sunny Ade kẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ, iyẹn pamari ati ileewe girama niluu Ondo, ti i ṣe ilu abinibi rẹ gan-an, o kuro nileewe girama, o ni oun fẹẹ lọ kawe giga ni fasiti Eko, iyẹn University of Lagos, UNILAG. Nigba to de ilu Eko ni nnkan mi-in wọ ọ, Eko si ni ibẹrẹ orin kikọ ati ere ṣiṣe ọmọ Adegẹye yii.

Laye igba naa, iwọnba lawọn oṣere to n da araalu laraya niluu Eko. Ọkan to gbajumọ daadaa ni Oloogbe Moses Ọlaiya tawọn eeyan mọ si Baba Sala. O maa n kọrin, amọ alawada ni, iṣẹ adẹrin-in poṣonu rẹ lo mu kawọn eeyan maa rọ lọọ woran rẹ nibikibi to ba pagbo ariya rẹ si laye ọjọun, Sunny Ade yii si wa lara awọn to maa n lọọ woran ọhun.
Nibi ka woran, ka gbadun ohun ta a wo, lo mu ki Sunny Ade di ọmọlẹyin Baba Sala, o darapọ mọ ẹgbẹ Moses Olaiya Federal Rhythm Dandies, ti wọn n kọrin afẹ, orin Highlife nigba yẹn, ibẹ lo si ti kẹkọọ beeyan ṣe n kọrin ati beeyan ṣe n jo daadaa, bo tilẹ jẹ pe oun naa ni ẹbun abinibi nipa orin kikọ ati ijo.

Lọdun 1967, iyẹn nigba tọjọ-ori rẹ ko ju ọmọọdun mọkanlelogun (21) pere lọ, Iṣọla Adegẹye kuro lẹyin Baba Sala, o lọọ da ẹgbẹ oṣere tirẹ silẹ, ṣe oun naa kuku ti n kọrin, o si ti n lero lẹyin diẹ diẹ, lo ba pe orukọ ẹgbẹ rẹ ni The Green Spots. Bọdun ṣe n gori ọdun, bi orin rẹ ṣe n tẹsiwaju, ti okiki rẹ si n pọ si i, bẹẹ lo n yi orukọ ẹgbẹ oṣere rẹ pada. Nigba kan, o yi i pada si African Beats, igba to si ya, o sọ ọ ni The Golden Mercury. Ninu awo orin rẹ kan lo ti kọrin pe:
Oluwa lo pe mi, lo yan mi wa,
Gbogbo awọn ayanfẹ ẹ lo ṣe logo
Idi niyi ta a ṣe porukọ wa ni Golden Mercury.
Kirakita ko ran o, girigiri ko ran an.

Bawo ni Sunny Ade ṣe waa di agba ọjẹ nidi ere Juju? Awo orin meloo lo ti ṣe? Awọọdu wo lo ti gba? Ajọṣe wo lo wa laaarin oun ati olorin Juju ẹlẹgbẹ rẹ kan, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi?  Ija oun ti Dele Abiọdun ti wọn n pe ni Adawa Super atawọn onijuuju mi-in nkọ? Ki lo mu ki orin Sunny Ade jẹ manigbagbe lọdọ awọn ololufẹ rẹ titi doni-in?
Ẹ pade wa ninu apa keji itan igbesi-aye Ọba orin olohun-iyọ yii, King Sunny Ade.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search