Itafaaji

Ori ko Portable olorin yọ lọwọ janduku l’Ekoo

Owe Yoruba to ni iku ti iba pa’ni, to ba ṣi ni fila, o t’ọpẹ, owe naa ti ṣẹ mọ gbajugbaja onkọrin taka-sufee ilẹ wa kan tọrọ gbogbo ki i se lori alabahun rẹ, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, tawọn tun mọ si Portable zah zuu zeeh, lara, pẹlu bi ori ṣe ko o yọ lọwọ awọn ọmọ ganfe ti wọn gẹgun-un de e nigba to lọọ kọrin fun ọrẹ rẹ kan lagbegbe Iju-Iṣaga, nipinlẹ Eko, lopin ọsẹ to lọ yii, diẹ lo ku ki wọn ṣe ọkunrin to fẹran lati maa daṣa “wahala, wahala, wahala” yii ṣika-ṣika, amọ sibẹ naa, ọgọọrọ awọn alatilẹyin rẹ ni wọn fara kaaṣa, awọn dukia rẹ kan si lọ si i.

Portable in distress

Ṣe ẹnu ọlọfa la a tii gbọ ‘mo ta a,’ Portable funra rẹ, to tun maa n pe ara rẹ ni ‘Ika of Africa’ lo royin ohun to ṣẹlẹ si i, ati gbogbo nnkan toju rẹ ri lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ta a wa yii, lori ikanni instagiraamu rẹ, lori ẹrọ ayelajura.

Yatọ si tawọn dukia rẹ kan to ni wọn dawati lasiko tawọn ọmọ ganfe naa ya bo o bii eeṣu, o lawọn ọmọọṣẹ oun kan wa toun ko ti i foju kan titi di ba a ṣe n sọ yii, tori niṣe lọrọ di bo-o-lọ-o-ya’go, ẹni ori yọ, o dile, nigba ti lọgbọ-lọgbọ naa waye.

Bayii ni Idaamu Adugbo, ọmọ Fẹdira gọfumẹnti ṣe royin ohun to ṣẹlẹ, o ni: “Wahala, palaba nla waye lagbegbe Iju Iṣaga ta a ti lọọ ṣayẹyẹ pẹlu ọrẹ wa, Lincon to n ta mọto. Inu adugbo ta a ti n ṣariya lọwọ, ibẹ lawọn ẹgbọn adugbo kan ti waa ba wa o, a ko tii ri awọn ọmọlẹyin Zehnation kan di bayii o. Wọn ṣakọlu sawọn bọisi mi lẹyin tori ko mi yọ, ti mo raaye yọ pọrọ. Lincoln, ẹ ba mi sọ fawọn ẹgbọn adugbo yẹn ki wọn fi Ifẹoluwa Babatunde silẹ, ati iPhone meji pẹlu kaadi ATM mi o, ki wọn ba mi da a pada o.”

Ifẹoluwa

“A ti ri awọn foonu dullarboi ati ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, amọ a ko tii ri oun alara. A o tii ri bamidọla naa, mo gbọ pe wọn ṣakọlu si i pẹlu. Awọn oṣiṣẹ mi ti mi o ti i mọbi ti wọn wa niyẹn o, oju o nii ti wa o. Eṣu gidi lawọn ẹgbọn adugbo yẹn, bẹẹ ni wọn ṣe ja ṣeeni ọrun mi gba, ti wọn bọ goolu yẹri eti mi, pẹlu gbogbo bi mo ṣe fifẹ han si wọn, ti mo fun wọn lowo, gbogbo owo apo mi ni mo na fun wọn, wọn tun fẹ fipa ba baagi mi. Ha, ṣe ololufẹ ni ka pe awọn eleyii abi ọta…”

Bẹẹ ni Portable ke gbajare lori ẹrọ ayelujara.

Oriṣiiriṣii ọrọ ati ero lawọn ololufẹ Portable fi fesi si iṣẹlẹ to waye yii. Bawọn kan ṣe n kaaanu rẹ, bẹẹ lawọn mi-in n da a lẹbi, wọn ni oun ni ko mọwọn ara rẹ, inu wahala ti Ọlọrun ti fa a jade, to si fun un logo, oun lo tun n tori ara rẹ bọ ibẹ, bẹẹ lawọn mi-in n fi i ṣe yẹyẹ.

Edorado ni “o ṣetutu lanaa, wọn waa lu u ẹ lalubami loni-in” o si gbe ami ẹfẹ ati ẹrin keekee sabẹ ọrọ naa.

Moonthecreator ni “Gbajumọ tiẹ yii, niṣe ni wọn bi ẹ ko o le jiya”.

Tee_mi ni: “Kinniun ki i bẹru lati da nikan rin, ṣo o ri ibi to o ba ara ẹ bayii.

Ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Start typing and press Enter to search