Itafaaji

Ijọba fowo kun gbigba iwe aṣẹ irin-ajo siluu oyinbo

Awọn to n gbero lati gba iwe-aṣẹ irinna siluu oyinbo gbọdọ gbaradi lati san owo igbawe-aṣẹ tuntun, latari bijọba Aarẹ Bọla Tinubu ṣe fowo kun iye ti wọn n san tẹlẹ.

Ni bayii, ijọba apapọ orileede Naijiria ti kede pe ẹkunwo tuntun ti gori iwe-aṣẹ irin-ajo siluu oyinbo, eyi tawọn eleebo n pe ni pasipọọtu, wọn niye owo tawọn eeyan to ba fẹẹ gba iwe-aṣẹ naa yoo san ti yi pada, o ti lọ soke bayii, ayipada ọhun yoo si bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 yii, iyẹn ni nnkan bii ọsẹ kan sasiko ta a wa yii.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ni agbẹnusọ fun ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si iwọle ati ijade lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Immigration Service, DCI Kenneth Tyoapine Udo kede pe ijọba ti fọwọ si ẹkunwo fun awọn to ba fẹẹ gba iwe-aṣẹ irinna ọhun, ninu atẹjade kan to fi kọ lalẹ ọjọ Wẹsidee.

PRO Immigration, Kenneth Ufo

Ọgbẹni Kenneth Udo ni ẹkunwo waye lati le tubọ ro iwe-aṣẹ irinna silu oyinbo ọhun lagbara daadaa, ko si tubọ jẹ ojulowo si i.

O ni ni bayii, gbigba pasipọọtu ọlọdun marun-un to ni oju-iwe mejilelọgbọn ti kuro ni ẹgbẹrun lọna marundinlogoji ti wọn n gba a tẹlẹ, o ti di ẹgbẹrun lọna aadọta bayii, (N50,000). Pasipọọtu oloju-iwe mẹrinlelọgọta ti iwulo rẹ jẹ ọlọdun mẹwaa ti fo soke si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un, dipo ẹgbẹrun lọna aadọrin naira ti wọn n gba a tẹlẹ.

Amọ ṣa o, fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa lẹyin odi lasiko yii, ẹkunwo yii ko kan wọn, ijọba ni iye ti wọn n gba a tẹlẹ niluu ti koowa wọn wa naa ni wọn yoo ṣi maa gba a ni tiwọn.

Nipari ikede ọhun, Agbẹnusọ Udo ni ijọba tọrọ aforiji fun aifararọ ti ẹkunwo ati ayipada yii le mu ba awọn araalu ti wọn fẹẹ gbawe-aṣẹ naa, bẹẹ nijọba ṣeleri lati tubọ mu eto iṣiṣẹsin awọn araalu lọkun-un-kundun si i, wọn lawọn o ni i figba kan bọkan ninu, bẹẹ ni iṣẹ wọn yoo tubọ maa kunju oṣuwọn ju ti tẹlẹ lọ. 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search