Aka-i-ka-tan lawọn eeyan to pesẹ, lara wọn ni awọn eekan oṣere tiata bii Ibrahim Chatta, Ọdunlade Adekọla, Fẹmi Adebayọ tawọn eeyan mọ si Jẹlili oniso, Toyin Abraham, ti wọn n pe ni Iya Ire ati ọkọ rẹ, Kọlawọle Ajeyẹmi, Ibrahim Yekinni Bakare tawọn eeyan tun mọ si Itẹlẹ, Kelvin Ikeduba, Jide Awobọna, Gabriel Afọlayan, Muyiwa Ademọla ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn pesẹ sibi afihan naa.
Bi pọpọ-ṣinṣin ayẹyẹ naa ṣe n lọ lọwọ, Lateef Ademeji ṣe ohun ti ọpọ eeyan ko reti, o si ya wọn lẹnu gidi. Niṣe ni ọkunrin naa ṣadeede bọ sori pepele lati ba awọn to pesẹ sibẹ sọrọ, o fẹẹ fi imọlara rẹ han lori aṣeyọri fiimu Liṣabi ati bawọn ẹlẹgbẹ rẹ ṣe gbaruku ti i. Iyẹn kii ṣe tuntun, iru ọrọ idupẹ bẹẹ saaba maa n waye nibi ayẹyẹ sinima bii eyi.
Amọ bi Adedimeji ṣe n dupẹ lọwọ, to n wo ọtun, to n wo osi, to n kuru, to n ga lori pepele, lẹẹkan naa lo tẹriba mọlẹ, o tẹriba mọlẹ gidi ni o, diẹ lo ku ko dọbalẹ gbalaja, ko si gboju soke rara bo ṣe n fi ohun irẹlẹ patapata sọrọ, lawọn eeyan ba n ṣe kayeefi pe ewo lo tun n ṣẹlẹ yii, wọn n reti ohun to fẹẹ sọ tabi ṣe.
Lateef ni oun fẹẹ lo anfaani ọjọ naa lati tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan ti oun ṣẹ ni, o ni tọkan-tọkan, tinu-tinu loun fi bẹbẹ lọwọ awọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ oun kan, atawọn ololufẹ oun to ṣee ṣe ki oun ti kọsẹ lara wọn lasiko ti wọn n ya ere Liṣabi naa lọwọ. O loun ko ni in lọkan lati ṣẹ ẹnikẹni o, oun ko si jọ ara oun loju, tori ẹ, oun fi Ọlọrun bẹ wọn, bi iru ẹni bẹẹ ba wa, ki wọn jeburẹ, ki wọn fọwọ wọnu, ki wọn si dari ji oun, oun tọrọ aforiji wọn.