“Ẹloo, orukọ mi ni Funkẹ Akindele, ti inagijẹ rẹ n jẹ Jẹnifa. Oni ni ayajọ ajọdun ominira Naijiria. Naijiria o kuu ọjọọbi o. Mo gbadura pe orileede yii yoo goke agba. Mo mọ pe a maa sọ pe ojoojumọ naa la n sọ pe Naijiria ṣi maa daa, bẹẹ ni o, o ṣi maa daa, nitori ibi yii lemi n gbe ti mo ti n ṣe ọrọ-aje mi, ibi lawọn eeyan ti mọ mi, ti wọn n pe mi ni ‘Gbogbo bigz gẹlz’.”
Iwọnyi ni diẹ lara awọn ọrọ iṣiti ti gbajugbaja oṣere-binrin onitiata nni, Funkẹ Akindele, sọ lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii, ti i ṣe ayajọ ominira ọdun kẹrinlelọgọta orileede Naijiria.
Funkẹ, iya ibeji, sọrọ ọhun ninu fidio kan to gbe soju opo Instagiraamu rẹ, lati da awọn ololufẹ rẹ lara ya, ko si sọrọ imọkanle fun wọn lọjọ ominira ọhun.
O han gbangba pe niṣe ni ‘Sulia kẹn, Ayetoro kẹn’ gẹgẹ bii aṣa rẹ ninu fiimu Jẹnifa, diidi ṣe fidio naa, nitori imura rẹ. Yatọ si pe imura rẹ ṣafihan awọ funfun ati olomi ewe to jẹ ti asia orileede Naijiria, irisi Funkẹ naa paayan lẹrin-in, pelu bo ṣe kun iru ori rẹ si awọ ewe, bẹẹ lo lẹ aworan ilẹ Naijiria, iyẹn maapu Naijiria mọ ẹrẹkẹ rẹ osi, o wọ ẹwu alawọ ewe, ati ṣokoto funfun bakan naa, o si kọ ọrọ kan siwaju ẹwu polo ọhun, o ni: “Gbogbo eeyan lo nifẹẹ si Jenifa.”
Funkẹ tẹsiwaju ninu ọrọ iṣiti rẹ, lati fihan pe oun nifẹẹ orileede Naijiria dọkan, oun ko si gba a lero lati sa kuro niluu, tabi lati lọọ maa gbe orileede mi-in, o ni:
“Gbogbo eeyan lo fẹran Jẹnifa, a lawọn oṣiṣẹ to n ba wa ṣiṣẹ to to marundinlọgọrin (75) nilẹ yii ati lorileede Ghana, amọ eyi to pọ ju ninu wọn lo jẹ ọmọ Naijiria yii. Tori ẹ, emi ni temi o, mi o ni i japa, mi o ni i filuu silẹ lọọ ibikibi, mo mọ pe a n la ọpọ nnkan kọja, amọ mo nigbagbọ pe orileede yii ṣi maa dun, o maa goke.”
Bakan naa ni Funkẹ Akindele tun kọ ọrọ ikini kuu oriire ajọdun ominira kan sabẹ fidio to gbe sori ikanni rẹ ọhun, ohun to si kọ ko yatọ si ọrọ to sọ. O gboriyin fawọn ọmọ Naijiria, o loun mọ pe wọn ti la saa to le koko kọja, sibẹ ti wọn ko kaarẹ. O loun ṣajọyọ ẹmi ifayaran, wiwa nnkan tuntun ṣe ati ireti wọn. O loun n wo ṣakun orileede Naijiria nibi ti ala rere yoo ti pọ yanturu, ti ẹbun abinibi kaluku yoo ti gberu. O si kadii ọrọ rẹ, o ni: “Ẹ jẹ ka nigbagbọ pe ọla n bọ waa daa!”