Itafaaji

Ọfọ ṣẹ lagbo tiata, gbajumọ oṣere dagbere f’aye!

Eyin ka, ile ẹrin wo, aferemojo ku, ẹnu isa n ṣọfọ! Ọrọ yii lo ṣe wẹku pẹlu bi awujọ awọn oṣere tiata ilẹ wa kan gbinri-gbinrin, to ọpọ lara wọn si fajuro pẹlu iyanu ati ijaya, nigba ti wọn gbọ nipa iku airoti to tun gbọna ẹburu wole saarin wọn, to si mu gbajumọ oṣere kan, Oloye Alaaji Mudashir Ayọbami Ọlabiyi, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Bọbọ B, lọ, ọkunrin naa ku lojiji.

ITAFAAJI fidi rẹ mulẹ pe ileewosan aladaani kan, to wa lagbegbe Amuloko, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni baba naa mi eemi ikẹyin si l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to fura si i, a gbọ pe aisan ọlọjọ pipẹ kan ti n ba ẹẹkan oṣere naa finra, to si ti kọkọ n ṣetọju rẹ bọ wẹrẹwẹrẹ labẹle, amọ nigba to ya, ni nnkan bii oṣu meji sẹyin, wọn gbe e lọ si ile iwosan nla ti Fasiti Ibadan, iyẹn UCH (University College Hospital).

Ọsibitu yii ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe arun itọ ṣuga tawọn eleebo n pe ni diabetes miletus ti kọle si Baba agbalagba naa lara ti ko si tete fura. Eyi lo jẹ ki wọn gba a wọle si ẹka ti wọn ti n ṣetọju awọn ti aisan wọn nilo itọju to lọọrin, ni ICU, Intensive Care Unit, wọn si sapa gidigidi lati du ẹmi rẹ ni gbogbo asiko to lo nibẹ.

A gbọ pe nigba t’awọn mọlẹbi rẹ woye pe ara ẹni wọn yii ko kọfẹ pada to bo ṣe yẹ ni wọn tun fi gbe e lọ si Amuloko, amọ aisan lo ṣe e wò, ko sẹni to ri t’ọlọjọ ṣe.

Ninu atẹjade kan ti Gomina ẹgbẹ awọn oṣere tiata, Theatre Arts And Motion Pictures Practitioners Association Of Nigeria (TAMPAN) nipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Bọsẹ Akinọla, fi lede nipa iṣẹlẹ yii, o fidi iku Bọbọ B mulẹ, o si kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi rẹ. O ni iku oloogbe naa jẹ adanu nla lagbo awọn oṣere tiata ilẹ wa, pẹlu afikun pe, Oloogbe yii ni akọwe ẹgbẹ awọn tẹlẹ.

ITAFAAJI tun fìdí rẹ mulẹ pe wọn ti sinku Bọbọ B laṣaalẹ ọjọ Wẹsidee, ni ilana ẹsin musulumi.

Ọpọ fiimu agbelewo ati ere ori itage ni Oloogbe naa ti kopa nigba aye rẹ, o si ja fafa loko ere.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search